Mo le fọwọ sọya pe gbogbo ileri ti mo ṣe fawọn ọmọ Naijiria ni mo ti mu ṣe fun wọn - Buhari sọrọ, ilẹ kun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, February 12, 2023

Mo le fọwọ sọya pe gbogbo ileri ti mo ṣe fawọn ọmọ Naijiria ni mo ti mu ṣe fun wọn - Buhari sọrọ, ilẹ kun


Aarẹ orileede Naijiria, Ọgagun Muhammadu Buhari ti sọ pe idunnu nla lo jẹ foun pe gbogbo awọn ileri toun ṣe f'awọn ọmọ Naijiria lakoko ipolongo idibo aarẹ lọdun 2015 loun ti mu ṣẹ lai ku ẹyọkan ṣoṣo.
 
Aarẹ Buhari lo sọ eyi di mimọ lọjọ Abamẹta, Satide ana ninu ọrọ to fi ranṣẹ si ibi ayẹyẹ ikẹkọọgboye fasiti apapọ to wa niluu Ọyẹ Ekiti, ipinlẹ Ekiti.

Nibẹ lo ti sọ pe iṣejọba oun ti pegede lawọn ẹka bii ọrọ aje, ipenija abo ati gbigbogun ti iwa ajẹbanu, gẹgẹ bi ileri to ṣe nigba to de ori oye.

Bakan naa lo tun sọ pe awọn nnkan mẹta yii ni oun gbe awọn ileri ti oun ṣe lasiko ipolongo ibo oun le, oun si ti ṣe aṣeyọri nlanla lawọn ẹka naa.

Buhari ni lootọ orilẹede Naijiria ko tii de ilẹ ileri, sibẹ ijọba oun ti fi ẹsẹ Naijiria le ọna idagbasoke ti ko ṣee yipada mọ bayii nipasẹ awọn eto idagbasoke to mu igbayegbadun araalu lọkunkundun.

Aarẹ Buhari sọ pe, 
“Mo fẹ ran gbogbo yin leti pe lasiko ti mo n ṣe ipolongo ibo lati di aarẹ lọdun 2015, mo ṣeleri lati mu atunṣe ba eto aabo, mu ọrọ aje gbopọn sii ati didojukọ iwa ajẹbanu. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe mo lee fi ọwọ sọya pe mo ti pegede lawọn ileri mẹtẹẹta yii.
 
“Nigba ti mo gba ijọba, irọkẹkẹ awọn agbesunmọmi atawọn ipenija eto abo miran ti ṣu bo orilẹede yii. Laifọtape, mo lee sọ pe a ti gbogun ti iwa igbesunmọmi, a si ti bori rẹ, pẹlu bi a ṣe gba gbogbo awọn ilu ti awọn agbesunmọmi gba pada. Lọwọ yii asiko ikẹyin ni fun iwa igbesunmọmi lorilẹede Naijiria.”
 
Bẹẹ lo tun fi kun un pe iṣejọba oun tun ti ṣe gudugudu meje yaayaa mẹfa lẹka eto ẹkọ nipa mimu afikun ba iye owo iyasọtọ fun eto ẹkọ ninu eto iṣuna ọdọọdun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI