Nitori aye to su, Destiny, akẹkọọ Yabatech l'Ekoo gbe oogun apẹfọn 'Sniper' mu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, February 11, 2023

Nitori aye to su, Destiny, akẹkọọ Yabatech l'Ekoo gbe oogun apẹfọn 'Sniper' mu


Kani kii ṣe ori to ko akẹkọọ ile ẹkọ
Yaba College of Technology, ti awọn eeyan tun mọ si YABATECH yọ lọwọ iku ojiji ni, o ṣee ṣe ko ti maa ba awọn ẹbọra jẹun lasiko ti a pari akojọ[pọ iroyin yii.
 
Ọjọru, Wẹsidee to kọja yii la gbọ pe Destiny gbe igbesẹ lati gb'ẹmi ara rẹ lojiji, ṣugbọn ti Ọlọrun fi ọkan lara awọn ọrẹ rẹ gaari tira ti ko jẹ ko gbabẹ sọda s'ọrun alakeji.
 
AWIKONKO gbọ pe Destiny, to wa ni ipele akọkọ, ẹka ikẹkọọ Marketing ko ba ẹnikẹni sọrọ lori awọn ohun to n la kọja, ati idi pataki to fi fẹẹ gba ẹmi ara rẹ.

Wọn ni ko pẹ to gbe oogun apẹfọn naa mu ni ọkan lara awọn ọrẹ rẹ ti wọn jọ n gbe wọle, to si ba a nibi to ti n pokaka iku, ko to di pe o pariwo sita.

Ariwo naa lo mu k'awọn to wa nitosi sare yọju, ti wọn si gbe e lọ si ile itọju ti ile ẹkọ naa fun itọju.

Lori awuyewuye to n lọ nipa wi pe ọmọbinrin naa ti ku, ati lori idi pataki to fi gbe majele mu, awọn alakoso ile ẹkọ ti ṣalaye pe ko si otitọ ninu awuyewuye to n kaakiri naa.

Igbakeji ọga agba igbaniwọle sile ẹkọ naa, Ọgbẹni Joe Ejiofor sọ pe Destiny ṣi wa laye, o wa nibi to ti n gba itọju lọwọ, ati pe awọn eeyan rẹ ti wa nibi to ti n gba itọju.
 
Ejiofor ṣalaye wi pe ko si otitọ kankan ninu awuyewuye wi pe wọn ka Destiny pẹlu iwa ijiwewo, tabi pe ololufẹ rẹ jaa ju silẹ, o ni ara rẹ ti n balẹ, ti ko si ni pẹ ẹ bẹrẹ eto ẹkọ rẹ pada lẹkunrẹrẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI