Nitori aitete ri owo san, awọn ajinigbe pa Akinọla danu l'Ondo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 10, 2023

Nitori aitete ri owo san, awọn ajinigbe pa Akinọla danu l'Ondo


Awọn ajinigbe kan la gbọ pe wọn ti pa baale ile kan, Akinọla Akinnibinudanu, lori ẹsun aitete ri owo ti wọn n beere gba lọwọ awọn mọlẹbi ẹ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Akinọla, ẹni ti wọn ni ko niṣẹ meji to kọja iṣẹ agbẹ n'ijọba ibilẹ Ondo East la gbọ pe wọn pa danu, lẹyin ti wọn jiigbe.
 
Yatọ si pe wọn pa Akinọla, ẹni ogoji ọdun danu, wọn ni niṣe ni wọn tun da kẹmika si oku rẹ lara, ko ma ba maa run pa wọn lagbegbe naa.
 
Ọjọru, Wẹsidee, ọsẹ yii ni AWIKONKO gbọ pe wọn ṣẹṣẹ ri oku Akinọla, lẹyin ọjọ mẹrin ti wọn lawọn ajinigbe naa ri pe iyawo ẹ, ti wọn si n beere owo.
 
Inu oko Akinọla to wa ni Oko Ọparun la gbọ pe wọn ti jii gbe, ti wọn si n beere ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin (N700,000) naira.
 
Wọn ni Akinọla ti pe iyawo rẹ wi pe ko lọ ya owo naa lọwọ awọn to n fi owo dokoowo, iyẹn POS to wa nitosi, ko si ko o wa lati fi doola ẹmi oun.
 
Wọn tun ni awọn ajinigbe naa pe iyawo Akinọla lati fi ọhun ranṣẹ sinu apo aṣuwọn OPAY kan ti wọn fi ranṣẹ sii, ṣugbọn kaka ko ṣe bẹẹ, wọn ni ọdọ awọn ẹṣọ aabo Amọtẹkun lo gba lọ lati fi to wọn leti.
 
Si iyalẹnu, wọn ni kawọn Amọtẹkun too debẹ, awọn ajinigbe naa ti juba ehoro.
 
Iyawo Akinọla ninu ọrọ rẹ sọ pe "Aarọ ni ọkọ mi jade nile wi pe oun n lọ si oko. Ko pẹ lo pe mi pe ki n lọ ba oun gba owo wa lọdọ ẹni to n ṣe POS nitosi ọdọ wa. Mo beere nnkan to fẹẹ fi aduru owo naa ṣe, ṣugbọn niṣe lo sọ pe ki n ma beere lọwọ oun, ati pe ti mo ba ko owo naa de, oun yoo maa ṣalaye fun mi.
 
"Igba to ya lawọn kan tun fi foonu ọkọ mi pe mi pe ki n fi owo naa ranṣẹ sinu aṣuwọn owo Opay kan. Wọn tun pe wi pe awọn ko tii ri owo naa, mo si sọ fun wọn pe mo ti fi ranṣẹ.
 

"Wọn sọ pe ki n maa bọ ninu oko yẹn. Aya mi ja, ẹru to si ba mi lo jẹ ki n lọ fi to awọn Amọtẹkun ati awọn ara abule leti.
 
"Bi emi ati awọn eeyan ṣe n bọ, wọn pe mi wi pe awọn sọ pe ki n maa bọ, mo tun lọ ko awọn eeyan dani lẹyin, wi pe awọn yoo fi aye han mi.
 
"Nigba ti a debẹ, a ko ri wọn,, eyi lo jẹ ka pada. Ana ni awọn eeyan pe ni lori foonu wi pe awọn ri oku ẹnikan ti wọn fi ewe imọ bo, wọn si ti da kẹmika si ara rẹ. Nigba ti mo debẹ, oku ọkọ mi ni mo ri."
 
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ti sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa, ati pe awọn ọlọpaa ẹkun Igba ti gbe oku naa lọ mọṣuari ijọba to wa niluu Ondo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI