Nitori gbajugbaja puromota, Ọmọrapala fẹẹ dalu bọlẹ l'Abẹokuta l'ọsẹ yii - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 27, 2023

Nitori gbajugbaja puromota, Ọmọrapala fẹẹ dalu bọlẹ l'Abẹokuta l'ọsẹ yii


Gbogbo eto lo ti pari bayii fun gbajugbaja olorin Fuji nni, Alaaji Abass Akande Obesere, ẹni ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Ọmọrapala lati dalu bọlẹ niluu Abẹokuta to jẹ olu-ilu ipinlẹ Ogun.

Obesere la gbọ pe o fẹẹ kọrin nibi ayẹyẹ ọjọ ibi gbajugbaja puromota olorin nni to filuu Abẹokuta ṣe ibugbe, Oloye Arẹmu Bamgboye, ẹni tọpọ mọ si Ajiki Olu.

Gbọngan ayẹyẹ ti DLK to wa lagbegbe Lẹmẹ, Abiọla-Way, iyẹn lẹgbẹ ileeṣẹ IBEDC ni ayẹyẹ ọjọ ibi ọhun ti fẹẹ waye, bẹrẹ lati aago mejila ọsan.

Ọjọ karun-un, oṣu kẹta, ọdun 2023 ti a wa yii la gbọ pe ọjọ ibi naa yoo waye.


Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ fi ye wa pe, awọn ọtọkulu lawujọ, ati awọn gbajugbaja l'agbo oṣere nilẹ Naijiria, ati loke okun ni wọn yoo wa nibi ayẹyẹ naa.

A tiẹ gbọ pe ọpọ awọn ololufẹ Ajiki Olu lati ilẹ Amẹrika, London, Dubai ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn ti bẹrẹ sii wọlu Abẹokuta lati ba agba puromota naa yọ.

Odu ni Ajiki Olu, kii ṣaimọ foloko, ẹni to ti gbe ọpọ awọn gbajumọ olori Fuji, Isilaamu, Igbagbọ ati bẹẹ bẹẹ lọ jade sigboro aye.


Yatọ si Ọmọrapala to fẹẹ dalu bọlẹ, a tun gbọ pe gbajumọ olori Isilamu nni, Alaaja Awoṣifa naa yoo kọrin lati da awọn alejo lara ya lọjọ naa.

Ẹ wa gbọ o, aṣọ funfun ati fila/gele buluu to tun ni goolu lara ni awọn eeyan yoo fi wọle sinu gbọngan ayẹyẹ lọjọ.

Pabambari ẹ ni ti eto aabo to ti wa nilẹ ni sẹpẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI