Nitori iwadii oku to sọnu ni mọṣuari, awọn oṣiṣẹ ọsibitu Ọlabisi Ọnabanjọ l'Ogun lu awọn akọroyin lalubami - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, February 4, 2023

Nitori iwadii oku to sọnu ni mọṣuari, awọn oṣiṣẹ ọsibitu Ọlabisi Ọnabanjọ l'Ogun lu awọn akọroyin lalubami


Awọn oṣiṣẹ-kọroyin meji kan ko le gbagbe ọjọ t'awọn oṣiṣẹ ọsibitu olukọni ti Ọlabisi Ọnabanjọ, iyẹn Olabisi Onabanjo University Teaching Hospital (OOUTH) to wa niluu Ṣagamu, ipinlẹ Ogun lu wọn lalubami, ti wọn tun ṣe wọn leṣe, iyẹn l'ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.
 
Yatọ si pe wọn lu wọn lalubami, a gbọ pe wọn tun ba awọn irinṣẹ iroyin wọn bii kamẹra ati awọn nnkan miran jẹ kọja atunṣe.
 
Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni iroyin kan jade sita wi pe oku poora ni mọṣuari ọsibitu naa, nigba tawọn to ni oku ọhun fẹẹ gbe e lati lọ ṣẹyẹ ikẹyin, ko to di pe wọn tẹ ẹ si afẹfẹ rere fun un, ṣugbọn to jẹ kayeefi wi pe wọn ko ri oku ọhun.
 
Iroyin ọhun ti AWIKONKO naa gbe lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.
 
A gbọ pe iwadii ohun to ṣẹlẹ lawọn akọroyin ileeṣẹ tẹlifiṣan nla kan nilẹ Adulawọ, iyẹn Afrika lọ ṣe, ko to di pe awọn tọọgi ti wọn pe ara wọn ni oṣiṣẹ eleto aabo ọsibitu naa kona iya fun wọn.
 
Ṣaaju asiko naa, a gbọ pe b'awọn akọroyin meji ọhun ṣe de sibẹ, ni wọn lọ si ọfiisi ọga agba ati agbẹnusọ, to fi mọ awọn alẹnulọrọ ọsibitu ọhun, lati ṣalaye nipa ohun ti wọn ba wa.
 
Iyalẹnu lo jẹ wi pe ko sẹni to ṣetan lati ba wọn sọrọ lori iṣẹlẹ naa, eyi lo fa a ti wọn fi pinnu lati ya ayika ọgba, paapaa mọṣuari ti iṣẹlẹ ọhun ti waye sinu kamẹra wọn.
 
Eyi ni wọn lawọn tọọgi ti wọn pe ara wọn ni oṣiṣẹ aabo naa ri, ti wọn si lọ kọlu wọn, ko to di pe wọn bẹrẹ sii da igbaju ati igbaju bo wọn. Alubami, to si ku diẹ ki wọn daku ni wọn lu wọn.
 
Lara awọn to n kọja lọ, iyẹn awọn ero to ṣẹṣẹ n dari bọ lati mọṣalaṣi, nibi ti wọnn ti lọ kirun Jimọ ni wọn sare sibi ikọlu naa lati gba awọn mejeeji silẹ.
 
Awọn ẹlẹyinju aanu to ri bi nnkan ṣe ri ni wọn tun ranṣẹ pe awọn ọlọpaa to wa nitosi lati wa doola ẹmi awọn akọroyin naa, ki wọn ma ba a pa wọn danu.
 
Awọn ọlọpaa lo pada ko wọn lọ teṣan wọn to wa lagbegbe Isalẹ Ọkọ, nibi ti wọn ti lọ ṣalaye ohun to ṣẹlẹ ko to di pe wọn gba beeli ara wọn lati maa lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI