Nitori owo naira tuntun ti ko fẹẹ gbe jade f'awọn araalu, ọga banki FCMB wọ gau l'Oṣogbo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, February 4, 2023

Nitori owo naira tuntun ti ko fẹẹ gbe jade f'awọn araalu, ọga banki FCMB wọ gau l'Oṣogbo


Ko tii daju pe ọkan lara awọn ọga ile ifowopamọ First City Monument Bank, iyẹn FCMB to wa niluu Oṣogbo ko ni f'oju winna ofin, lori bo ṣe ko idaamu ba awọn araalu ti wọn fẹẹ gba owo naira tuntun lẹnu maṣiini ATM to n pọ owo jade.
 
Ọwọ awọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti lilo owo lọna aitọ ati iwa jibiti lorileede yii, iyẹn Independent Corrupt Practices and Other Related Offences Commission, ICPC lo tẹ ọga banki naa, nitori owo naira tuntun ti ko fẹẹ ko jade sita f'awọn eeyan lati gba.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ajọ naa lo ti paṣẹ wi pe ki gbogbo banki ko owo tuntun sita, paapaa lẹnu ATM wọn, f'awọn araalu lati gba, ki wọn le ri owo na.

Ninu atẹjade ti ajọ ICPC gbe jade lọjọ Ẹti, Furaidee ana loju opo Twitter wọn, wọn jẹ ko ye wa pe niṣe ni ọga banki naa fi ọra [nylon] we awọn owo naira tuntun ti wọn ko s'ẹnu ATM, eyi ti ko le jẹ k'awọn maṣiini naa pọ owo jade sita f'awọn eeyan.
 
Wọn ni iwadii ti bẹrẹ lori ọga banki naa, nitori pe o ti wa lahamọ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI