O pari! Wọn ju aburo iyawo Aarẹ Ọbasanjọ tẹlẹ sẹwọn ọdun meje lori ẹsun jibiti - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, February 19, 2023

O pari! Wọn ju aburo iyawo Aarẹ Ọbasanjọ tẹlẹ sẹwọn ọdun meje lori ẹsun jibiti


Onidajọ Mojisọla Dada ti ile ẹjọ ẹsun to ṣara ọtọ, iyẹn, Special Offenses Court to wa niluu Ikẹja, ipinlẹ Ekoo ti ju Ọmọwe
John Abebe, sẹwọn ọdun meje gbako pẹlu iṣẹ aṣekara lori ẹsun jibiti ati yiyi iwe.
 
Ọmọwe Abebe ni aburo iyawo Aarẹ tẹlẹri lorileede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, iyẹn Oloogbe Stella Ọbasanjọ, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
Lara awọn ẹsun ti wọn tun fi kan ọkunrin naa ni gbigbe owo kaakiri lọna aitọ, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni 'money laundering'.
 
Ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu kumọkumọ ti a mọ si Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) lo wọ baba naa lọ sile ẹjọ yii, pẹlu awọn ẹri to fẹsẹ mulẹ daadaa.
 
Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu keje, ọdun 2018 la gbọ pe Abebe kọkọ foju ba ile-ẹjọ naa pẹlu ẹsun mẹrin ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu jibiti.
 
A gbọ pe ileeṣẹ kan to n ṣoowo epo rọbii, ti wọn pe ni Statoil Nigeria Limited lo fẹsun jibiti kan Ọmọwe Abebe lọjọ kejilelogun, oṣu kẹfa, ọdun 2010.
 
Wọn ni niṣe lo lọ ṣe ayidayida iwe adehun kan ti ajọ Net Profit Interest Agreement (NPIA) kọ lọgbọn ọjọ, oṣu kọkanla, ọdun 1995, eyi ti ileepo ilẹ Britiko, iyẹn British Petroleum (BP) ti kọkọ kọ jade.
 
Abala kan nibẹ la gbọ pe Ọmọwe Abebe ṣe ayipada rẹ lati maa fi lu jibiti kaakiri, eyi ti ko ni jẹ ki ile-ẹjọ fọwọ kan an, nigba ti ọrọ ba di wahala fun un.
 
Onidajọ Mojisọla Dada nigba to n gbe idajọ naa kalẹ wa fi aaye silẹ fun owo itanran aadọta miliọnu naira, to si gbọdọ san laaarin oṣu kan gbako, bi bẹẹ kọ, ko lọ fẹsun ọdun meje gbako gbara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI