Nitori ọrọ to sọ nipa owo naira atijọ, ipinlẹ mẹwaa gbe Buhari lọ sile ẹjọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, February 19, 2023

Nitori ọrọ to sọ nipa owo naira atijọ, ipinlẹ mẹwaa gbe Buhari lọ sile ẹjọ


Ko din ni ipinlẹ mẹwaa ti wọn tun ti gbe Aarẹ Muhammadu Buhari ti orileede Naijiria lọ sile ẹjọ lori awọn ọrọ to sọ nipa gbedeke nina owo naira atijọ, ẹẹdẹgbẹta ati ẹgbẹrun kan naira.
 
Ile-ẹjọ agba pata lorileede yii lawọn ipinlẹ naa gbe Aarẹ Buhari lọ lati yi ọrọ rẹ to sọ l'Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee to kọja yii, ti wọn si ni awọn ọrọ naa ko ba ofin mu.
 
Agbẹjọrọ awọn ipinlẹ naa, A.J. Owonikoko (SAN), ṣalaye pe Buhari tako abala 232(1), abala 6(6)(b) ati abala 287(1) ninu iwe ofin orileede Naijiria, tọdun 1999, lori ẹsun mejila ọtọọtọ ti wọn gbe lọ. 
 
Yato si agbẹjọrọ naa, awọn adajọ agba n'ipinlẹ mẹwẹẹwa bii Kaduna, Kogi, Zamfara, Ondo, Ekiti, Katsina, Ogun, Cross River, Sokoto, ati Ekoo wa lara olufisun, nigba ti adajọ agba pata lorileede Naijiria, Abubakar Malami (SAN), ati awọn adajọ nipinlẹ Bayelsa ati Edo jẹ gẹgẹ bi awọn ti wọn fẹsun kan.
 
Ninu ẹsun naa ni wọn ti sọ pe bi Buhari ṣe sọ pe igba naira owo atijọ loun faaye silẹ fun lati na fun ọgọta ọjọ, ti o si gbegi dina ẹẹdẹgbẹta ati ẹgbẹrun kan naira ko ba ofin mu, paapaa o tun tako aṣẹ ile ẹjọ agba naa, nitori pe ẹjọ naa ṣi wa ni kootu ko to di pe Buhari tun sọrọ jade.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI