Ọṣun: Adeleke tun lulẹ nile ẹjọ agba Naijiria l'Abuja - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 2, 2023

Ọṣun: Adeleke tun lulẹ nile ẹjọ agba Naijiria l'Abuja


Ile ẹjọ giga agba lorileede Naijiria ti da ẹsun ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP pe lati tako bi Gboyega Oyetọla ṣe di oludije sipo gomina nipinlẹ Ọṣun ati igbakeji rẹ, Benedict Alabi, ninu eto idibo ọdun 2022 to waye.

Onidajọ Emeka Nwite ti ile ẹjọ giga Abuja, paṣẹ lọgbọn ọjọ, oṣu kẹsan, ọdun 2022 wi pe Oyetọla ati igbakeji rẹ, Alabi ko lẹtọọ lati kopa ninu eto idibo gomina lọdun to kọja.

O ni fọọmu ti wọn gba lati fi dupo lo jẹ pe alaga fidihẹ f'ẹgbẹ oṣelu APC, ẹni to tun jẹ gomina ipinlẹ Yobe, Mai Mala Buni lo bu ọwọ luu
 
Eyi lo mu ko gbe idajọ naa kalẹ, ṣugbọn ti ile ẹjọ kotẹmilọrun pada da idajọ naa nu l'oṣu kejila, ọdun to kọja.

Nigba to n gbe idajọ naa kalẹ lonii, Ọjọbọ, Tọsidee, Onidajọ Centus Nweze sọ pe ẹsun naa ko l'ẹsẹ nilẹ daadaa, to si paṣẹ pe ki agbẹjọro PDP, Kẹhinde Ogunwumiju (SAN), yọwọ lori ẹjọ naa.

Onidajọ Nweze sọ pe PDP ko lẹtọọ labẹ ofin lati tako oludije ninu ẹgbẹ oṣelu miran, paapaa bi Oyetọla ati Alabi ṣe wọle.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI