Owo Naira tuntun: Buhari fẹẹ b'awọn ọmọ Naijiria sọrọ laarọ oni - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 16, 2023

Owo Naira tuntun: Buhari fẹẹ b'awọn ọmọ Naijiria sọrọ laarọ oni


Aago meje oni, ỌJọbọ tii ṣe Tọsidee ni Aarẹ orileede Naijiria, Muhammadu Buhari fẹẹ ba gbogbo ọmọ ilẹ naa sọrọ, lori ipinnu ati erongba rẹ lori gbogbo rogbodiyan to n ṣẹlẹ kaakiri lori ọwọngogo epo rọbii ati owo naira tuntun.
 
Ori ikanni agbẹyẹfo ti Twitter ni ijọba Naijiria ti kede iroyin naa, ti wọn si ni ki gbogbo araalu farabalẹ lati gbọ ohun ti Aarẹ Buhari fẹẹ ba wọn sọ.
 
Gbogbo awọn ileeṣẹ amohunmaworan ati igbohunsafẹfẹ patapata kaakiri orileede yii ni wọn rọ lati gbe ọrọ Aarẹ sita f'awọn araalu lati wo, ki wọn si gbọ.
 
Ikanni amohunmawora ijọba apapọ, iyẹn Nigeria Television Authority, NTA, ati agbohunsafẹfẹ ti Radio Nigeria ni Aarẹ Buhari yoo lo lati sọrọ rẹ, ti awọn yooku yoo si darapọ mọ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI