Aye o! Eeyan mẹfa ku, awọn mẹsan farapa nibi ijamba ọkọ to waye n'Ilọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 16, 2023

Aye o! Eeyan mẹfa ku, awọn mẹsan farapa nibi ijamba ọkọ to waye n'Ilọrin


Ko din ni eeyan mẹfa ti wọn padanu ẹmi wọn l'Ọjọru tii ṣe Wẹsidee, ọsẹ yii, ninu ijamba mọto to waye lagbegbe Ganmo, opopona Ilọrin si Omu-Aran, ipinlẹ Kwara.
 
Bọọsi alawọ eeru ti Suzuki kan ti nọmba idanimọ rẹ jẹ BDJ-134XB ati tirela DAF alalubọsa ti nọmba rẹ jẹ ABC435XN, eyi to n bọ lati ipinlẹ Ṣokoto la gbọ pe wọn kọlu ara wọn.
 
Lara awọn to fi iṣẹlẹ naa to wa leti sọ pe ere asapajude lo ṣokunfa ijamba to ran eeyan mẹfa lọ sọrun aremabọ naa.
 
Alakoso ajọ ẹṣọ oju popona ti Federal Road Safety Corps, Ọgbẹni Ade Ogidan, to f'idi ijamba ọhun mulẹ ṣalaye pe yatọ si awọn mẹfa to gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra, awọn mẹsan-an miran tun farapa yannayanna.
 
Ogidan lo jẹ ka mọ pe eeyan mẹẹdogun lo fara kaaṣa ninu ọhun, ti gbogbo wọn si jẹ ọkunrin, ṣugbọn ti mẹfa dagbere faye, nigba t'awọn mẹsan yooku farapa kọja sisọ.
 
Bẹẹ lo fi ye wa pe ọsibitu ijọba t'awọn olukọni, iyẹn UITH to wa niluu Ilọrin l'awọn ko awọn to farapa naa lọ, nigba ti wọn ko awọn to padanu ẹmi wọn lọ si mọṣuari.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI