Owo Naira tuntun: Inu Aarẹ Buhari ko dun si wahala t'awọn ọmọ Naijiria n koju lasiko yii, o maa fi ọjọ kun nina awọn owo atijọ - Oṣiṣẹ pataki - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, February 15, 2023

Owo Naira tuntun: Inu Aarẹ Buhari ko dun si wahala t'awọn ọmọ Naijiria n koju lasiko yii, o maa fi ọjọ kun nina awọn owo atijọ - Oṣiṣẹ pataki


Bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii ba fi jẹ otitọ, a je pe asiko to fawọn ọmọ orileede Naijiria lati kuro ninu gbogbo rogbodiyan ati wahala ti wọn n koju lasiko yii.

Ọkan pataki lara awọn amugbalẹgbẹ Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ pe gbogbo laalaa ati wahala t'awọn araalu n koju ko tẹ Aarẹ lọrun, to si ti n wa ọna abayọ

Ẹni naa sọ pe Aarẹ Buhari ti n ronu lati fi ọgọta ọjọ, iyẹn oṣu meji gbako kun ọjọ ti awọn ọmọ Naijiria yoo fi na owo atijọ gbẹyin.

O ni eyi lo fẹẹ waye, lati fi opin si aitẹle aṣẹ ile ẹjọ agba lati bi ọjọ meloo sẹyin, wi pe awọn owo atijọ yoo ṣi maa jẹ nina.

Bẹ o ba gbagbe, CBN ti sọ pe aṣẹ ti ile ẹjọ gbe kalẹ wi pe k'awọn eeyan ṣi maa na owo naa lọ ko kan oun, ṣugbọn ọkan pataki lara awọn alẹnulọrọ lọdọ Aarẹ Buhari ti sọ pe ohun to n ṣẹlẹ s'awọn araalu n kọ Buhari lominu pupọ

O ni lara awọn ohun ti wọn sọ ree ninu ipade awọn gomina ilẹ Naijiria, Nigeria Governors Forum (NGF) ati Progressives Governors Forum (PGF) to waye lonii ni wọn ti mẹnuba ọrọ naa.
 
Siwaju sii lo sọ pe Aarẹ Buhari yoo sọrọ lori ipinu rẹ nipa ilana eto owo sita fun gbogbo araalu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI