Ọwọ tẹ ẹgbọn at'aburo lori ẹsun ipaniyan, idigunjale l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, February 18, 2023

Ọwọ tẹ ẹgbọn at'aburo lori ẹsun ipaniyan, idigunjale l'Ogun


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ ẹgbọn ati aburo kan, Damilọla Famọriyọ, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn ati aburo rẹ, Akinbayọ Emmanuel Abiọdun, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn lori ẹsun idigunjale ati ipaniyan.
 
Ẹnikan ti wọn pe ni Amos Oyemechi Chuckwuka la gbọ pe awọn mejeeji digun ja lole, wọn gba kẹkẹ maruwa to fi n ṣiṣẹ aje, wọn si tun pa a.

Ilu Ijẹbu-Ode la gbọ pe iṣẹlẹ ọhun ti waye, koda, a gbọ pe niṣe ni wọn tun ju oku Amos sinu odo ki aṣiri ma ba a tu sita.

Ọjọ kẹsan, oṣu keji, ọdun ti a wa yii ni iroyin fi to wa leti pe ọwọ ọlọpaa tẹ awọn mejeeji lẹyin ti iwadii f'idi rẹ mulẹ pe awọn ni wọn ṣiṣẹ buruku ọhun.
 
A gbọ pe awọn ọlọpaa ẹkun Ọbalende ni olobo naa tẹ lọwọ lọjọ kẹtala, oṣu kejila, ọdun 2022. Awọn kan ni wọn kofiri oku kan lẹgbẹ odo to wa ni Agoro, ti iwadii si pada f'idi rẹ mulẹ pe kẹkẹ maruwa ni oloogbe naa n wa.
 
Eyi lo jẹ ki awọn ọlọpaa bẹrẹ iwadii, ti ọwọ si tẹ Damilọla, ẹni to n gbe lagbegbe New site, Awosan Fakale niluu Ikorodu pẹlu foonu oloogbe naa.
 
Damilọla lo pada jẹwọ pe oun pẹlu Akinbayọ lawọn jọ pa Amos danu, koda, o sọ pe niṣe lawọn ṣaa ladaa, ko to di pe awọn ju oku rẹ sinu odo fun ẹja lati jẹ ẹ, lai mọ pe aṣiri maa pada tu.
 
Akinbayọ ni wọn loun n gbe ni Road 1, Block A, agbegbe Maya niluu Ikorodu.
 
Ninu atẹjade ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi fi ranṣẹ s'AWIKONKO, o ni awọn mejeeji lo ti jẹwọ pe lotitọ lawọn digun ja Amos lole, ti awọn si tun ṣeku pa a.
 
O ni yatọ si eyi, wọn tun jẹwọ pe awọn mejeeji ko niṣẹ meju ju ki wọn maa digunjale, ati pe ọkada ati kẹkẹ maruwa lawọn fẹran lati maa digun gba niluu Ijẹbu Ode ati agbegbe rẹ.

Bẹẹ ni wọn tun sọ pe ko din ni kẹkẹ maruwa mẹjọ ti wọn ti digun gba, ti awọn si lawọn to n ra a lọwọ wọn niluu Ikorodu.
 
Ni bayii, ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Frank Mba ti paṣẹ pe ki wọn tẹsiwaju iwadii, ki wọn si tete lọ foju wọn ba ile ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI