Ilu Ilawọ gbarada nibi ayẹyẹ ọdun Liṣabi ilu Ẹgba (Fọto) - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, February 18, 2023

Ilu Ilawọ gbarada nibi ayẹyẹ ọdun Liṣabi ilu Ẹgba (Fọto)


Gbogbo awọn ọba alaye ilẹ Ẹgba, to fi mọ awọn alẹnulọrọ, ati ọmọ ilu, pẹlu awọn alejo patapata ni wọ n gbe oṣuba kare fun ilu Ilawọ, ẹka kan lara awọn to sọ ilu Ẹgba papọ lori bi wọn ṣe gbarada nibi idije Balogun Wọrọ to waye lonii, nibi ayẹyẹ ọdun Liṣabi.
 
Kii ṣe ahesọ tabi asọdun wi pe eto ayẹyẹ ọdun Liṣabi, ẹlẹẹkẹrindinlogoji iru ẹ, to waye kaakiri ilu Abẹokuta lonii dun, o si larinrin.
 
Lara awọn to wa nibi aṣekagba ayẹyẹ ọhun to waye ninu gbagede ayẹyẹ ni aafin Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ ni Gomina Dapọ Abiọdun t'ipinlẹ Ogun, kọmiṣanna fọrọ aṣa ati irin ajo afẹ, Ọnarebu Adijat Adelẹyẹ ati awọn miran.
 
Yatọ si Alake, awọn ọba miran to tun wa nibẹ ni Olowu tiluu Owu, Ọba Matẹmilọla; Agura tiluu Gbagura, Ọba Saburee Babajide Bakre; ati Ọṣilẹ Oke Ọna Ẹgba. Awọn ọba mẹrin yii lo jẹ ọba alaye ilẹ Ẹgba.

Olu Itori, Ọba AbdulFatai Akorede Akamọ ati Iyalode ilẹ Yoruba, Oloye Arabinrin Alaba Lawson ko gbẹyin nibi eto ọhun, to fi mọ gbogbo awọn ọba patapata to wa niluu Ẹgba ati agbegbe rẹ.

Awọn oloye ati awọn alẹnulọrọ niluu Ẹgba, to fi mọ awọn araalu patapata ni wọn peju sibẹ.
 
Lara awọn alakalẹ eto ayẹyẹ naa ni gigun ẹṣin Balogun Wọrọ, ti wọn fi n ṣe iranti akanni to tẹ ilu Ẹgba do, iyẹn Liṣabi, eyi ti wọn maa n yan awọn to ba tọ laaarin ilu.
 
Ilu Ilawọ, ọkan pataki lara awọn ilu to wa labẹ Oke-Ọna Ẹgba naa ko gbẹyin nibi gigun ẹṣin Balogun Wọrọ t'ọdun yii, koda, ọba tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan fun ilu Ilawọ, Olunla Oke-Ọna Ẹgba, Oluṣẹgun Alexander Macgregor lo gun ẹṣin ọhun.

Bi wọn ṣe wọle sinu gbọngan ayẹyẹ naa ni awọn eeyan ti bẹrẹ sii gbe oṣuba kare fun wọn, nitori pe ọna ara ni wọn gbe Balogun Wọrọ wọn gba, pẹlu awọn ikọ akọwọrin rẹ.

Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Gbadebọ to fi mọ awọn ọba yooku ni wọn sọ pe ọna ti ilu Ilawọ gbe Balogun Wọrọ wọn gba, iru rẹ ko tii ṣẹlẹ ri.

Gomina Dapọ Abiọdun nigba to ri ohun to ṣẹlẹ sọ pe ko si nnkan toun tun n duro de, bi ko ṣe pe koun tete buwọ lu Macgregor gẹgẹ bi Ọba ilu Orile Ilawọ, nitori pe ẹni tawọn araalu n fẹ ni.

Nigba to n sọrọ, Oluṣẹgun Macgregor sọ pe ko jẹ iyalẹnu wi pe awọn ṣe ipo kinni nibi gigun ẹṣin Balogun Wọrọ fun ilu Oke-Ọna Ẹgba lọdun 2023, nitori pe ẹlẹṣin ni wọn nidile wọn.

O lawọn baba-nla oun maa n gun ẹṣin lati jagun ni, bo tilẹ pe nnkan ti yatọ lasiko ọlaju, sibẹ o ni ohun ti wọn fi kọ wọn lati kekere ni ẹṣin gigun ati itọju ẹṣin, paapaa ẹṣin funfun.

Siwaju sii lo dupẹ lọwọ Ọṣilẹ Oke-Ọna Ẹgba, Ọba Adedapọ Tẹjuoṣo ati awọn oloye ilu Oke-Ọna, to fi mọ gbogbo ọba alaye ati oloye ilu Ẹgba lapapọ, fun bi wọn ṣe fọwọ si oun gẹgẹ bi Balogun Wọrọ.

Bẹẹ lo ṣeleri pe oun yoo tubọ maa mu idagbasoke ba aṣa, iṣẹ ati iṣẹdalẹ ilu Ẹgba.

Bakan naa lo pe gbogbo ọmọ ilu Oke-Ọna Ẹgba ti wọn wa kaakiri agbaye lati ma ṣe gbagbe ile, paapaa ni iru awọn ayẹyẹ bayii.















No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI