Ọwọ ti tẹ gbogbo awọn afurasi to pa tọkọ-taya lọjọ ọdun tuntun l'Abẹokuta - Ọlọpaa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 9, 2023

Ọwọ ti tẹ gbogbo awọn afurasi to pa tọkọ-taya lọjọ ọdun tuntun l'Abẹokuta - Ọlọpaa


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti f'idi rẹ mulẹ pe gbogbo awọn to lọwọ ninu iku t'ọkọ t'iyawo, ati ọmọ wọn lọjọ aisun ọdun tuntun ti a wa yii lọwọ ti tẹ patapata, ti iwadii si ti n lọ lori wọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi lo f'idi ọrọ naa mulẹ loju opo Fesibuuku rẹ lọsan oni, Ọjọbọ, Tọsidee, to si lawọn eeyan naa ti wa lahaamọ wọn.

Bo tilẹ jẹ pe Abimbọla Oyeyẹmi ko tii sọ kulẹkulẹ bọwọ ṣe tẹ awọn afurasi ọdaran naa, ati iru eeyan ti wọn jẹ, sibẹ o jẹ ko di mimọ pe laipẹ laijinna, oun yoo ṣalayẹ lẹkunrẹrẹ.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI