Ọwọ ti tẹ Hassan lẹyin oṣu mẹta gbako to dana sun iyawo ẹ n'ipinlẹ Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 3, 2023

Ọwọ ti tẹ Hassan lẹyin oṣu mẹta gbako to dana sun iyawo ẹ n'ipinlẹ Ogun


Pakopako ni baale ile, ẹni ọdun mẹrindinlaadọta kan, Hassan Azeez n wo nigba tọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun tẹ ẹ lori ẹsun ipinnu lati ṣeku paayan, ẹni to tun jẹ iyawo ẹ.
 
Wọn ni Ọlọrun atijọ lo n pẹ ko to mu aṣebi, ṣugbọn Ọlọrun asiko yii kii pẹ rara ko to f'oju aṣebi han. Bẹẹ si ni ọrọ Yoruba kan to sọ pe 'ọjọ gbogbo ni t'ole, ọjọ kan ṣoṣo bayii ni t'olohun' lo lọ nibamu pẹlu bọwọ ṣe tẹ Hassan.
 
Hassan la gbọ pe o dana sun iyawo ẹ pẹlu epo bẹntiroolu ati iṣana lọjọ kejilelogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2022, to si ṣe bẹẹ na papa bora.

Ẹsun ti wọn ni Hassan fi kan iyawo ẹ ni pe ko tete dana ounjẹ fun un, to si fibinu da bẹntiroolu sii lara, ko to di pe o ṣana sii. Nigba to rii pe iyawo oun yoo gbabẹ sọda sọrun alakeji, lo ba na papa bora.

Awọn araadugbo la gbọ pe wọn ranṣẹ s'awọn obi obinrin naa, ti wọn si sare gbe e lọ si ọsibitu kan niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ lati doola ẹmi ẹ.

Ilu kan ti wọn n pe ni Ibogun ni iṣẹlẹ ọhun ti waye.

Nigba tọwọ palaba Hassan maa segi, ọjọ kejilelogun, oṣu kinni, ọdun yii, iyẹn ọjọ to pe oṣu mẹta gbako lọwọ tẹ ẹ, to si pada jẹwọ pe ilẹ olominira Bẹnin loun salọ nigba ti iṣẹlẹ ọhun waye, lai mọ pe ọwọ yoo pada tun tẹ oun.

Abimbọla Oyeyẹmi to jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa nigba to n fidi iroyin naa mulẹ, o sọ pe ọmọ kan ṣoṣo pere ni obinrin naa bi fun Hassan, to si maa n tori rẹ fi iya jẹ ẹ.

Bẹẹ lo sọ pe baba obinrin naa lo lọ fi ọrọ ọhun to awọn ọlọpaa leti, ko to di pe ọwo tẹ ẹ. Bẹẹ lo sọ pe Hassan ti wa nibi to ti n ṣalaye ohun to ri lọbẹ to fi waaru ọwọ.
 
Siwaju sii lo fi ye wa pe nigba ti Hassan n sọrọ, o loun sọ fun iyawo oun lati ba oun dana ounjẹ, ṣugbọn kaka ko dahun, niṣe lo n fi oun fọ aṣọ, eyi lo bi oun ninu, toun ṣe fibinu da bẹntiroolu lee lori, toun si ṣana sii.
 
O wa ni iṣẹ eṣu pọmbele ni, ki awọn ọlọpaa foju aanu wo oun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI