Nnkan de! Awọn agbebọn yawọ kootu, ni wọn ba yinbọn pa adajọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 3, 2023

Nnkan de! Awọn agbebọn yawọ kootu, ni wọn ba yinbọn pa adajọ


Iyalẹnu gbaa lọrọ awọn agbebọn kan tẹnikẹni ko tii mọ titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, ti wọn sọ pe wọn yinbọn pa adajọ ile ẹjọ kọkọkọkọ kan.
 
Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii la gbọ pe awọn agbebọn naa yawọ kootu yii to wa n'ijọba ibilẹ Oguta, ipinẹ Imo, ti wọn si pa alaga ile ẹjọ naa, Onidajọ Nnaemeka Ugboma.
 
Asiko ti wọn sọ pe igbẹjọ n lọ lọwọ ni iṣẹlẹ ọhun waye, eyi to mu ki kootu ọjọ naa fori ṣanpọn, nitori pe loju ẹsẹ lawọn eeyan ti juba ehoro lati doola ẹmi ara wọn.

Lara awọn to fi iṣẹlẹ ọhun to wa leti sọ pe ọlọmọ ko mọ ọmọ naa, nigba ti ikọlu ọhun waye, ti a si gbọ pe iwadii awọn ọlọpaa ti bẹrẹ lẹkunrẹrẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI