Tinubu lo ṣi n bori, pẹlu boun ati Atiku ṣe n lewaju ni Ijọba ibilẹ marun-un-marun-un ni Ṣokoto - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 27, 2023

Tinubu lo ṣi n bori, pẹlu boun ati Atiku ṣe n lewaju ni Ijọba ibilẹ marun-un-marun-un ni Ṣokoto


Bi kika esi idibo ṣi ṣe n lọ lọwọ kaakiri orileede Naijiria, oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress, Bọla Tinubu ati alatako rẹ lẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, Atiku Abubakar, ni wọn jọ n fi agba han ara wọn nipinlẹ Ṣokoto, pẹlu bi awọn mejeeji ti ṣe bori lawọn ijọba ibilẹ marun-un-marun-un.
 
Ijọba ibilẹ mẹtalelogun lo wa n'ipinlẹ Ṣokoto, ṣugbọn ni bayii, awọn oludije mejeeji yii ti ko ibo lawọn ijọba ibilẹ mẹwaa, pẹlu bi wọn ṣe ja a gba mọ ara wọn lọwọ.
 
Ju gbogbo rẹ lọ, Tinubu lo ṣi n lewaju lẹyin ti ajọ eleto idibo ka awọn ibo naa tan.
 
Ibo 101,608 ni Tinubu ni, nigba ti Atiku ni ibo 98,080. Kwakwanso ati Obi ni wọn n tẹle wọn lẹyin pẹlu ibo 324 ati 171 lawọn ijọba ibilẹ mẹwaa ti wọn ti ka naa.
 
Awọn ijọba ibilẹ ti wọn ti ka ni Shagari, Yabo, Gudu, Tangaza, Rabbah, Binji, Wurno, Tureta, Bodinga ati Kware.
 
Ibo kika ṣi n lọ lọwọ l'awọn ijọba ibilẹ mẹtala yooku.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI