Peter Obi bori bi Tinubu ṣe lulẹ l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 27, 2023

Peter Obi bori bi Tinubu ṣe lulẹ l'Ekoo


Oludije s'ipo aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi ti bori kaakiri ipinlẹ Ekoo nibi idibo apapọ to waye lopin ọsẹ to kọja yii.

Ijọba ibilẹ mẹsan ni Obi ti bori l'Ekoo, nigba ti Tinubu toun jẹ oludije s'ipo aarẹ labẹ asiaẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Bọla Tinubu mu ijọba ibilẹ mẹwaa.

Eyii lo f'idi mulẹ pẹlu bi ajọ eleto idibo, ẹka t'ipinlẹ Ekii ṣe ka esi abajade ibo l'awọn ijọba ibilẹ mọkandinlogun to wa l'Ekoo.

Awọn ijọba ibilẹ ti Obi ti bori ni; Ajerọmi-Ifẹlodun, Amuwo-Ọdọfin, Eti-Ọsa, Ikẹja, Koṣọfẹ, Oṣhodi-Isọlọ, Ṣomolu, Ọjọ ati Alimọṣhọ

Ijọba ibilẹ mẹwaa ti Tinubu ti bori ni; Agege, Apapa, Badagry, Ẹpẹ, Ibẹju-Lẹkki, Ifakọ-Ijaiye, Ikorodu, Lagos Island, Lagos Mainland, ati Surulere.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI