Wọn ni Ọba Akinolu yẹyẹ Peter Obi, o loun ko fẹẹ rii soju - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 13, 2023

Wọn ni Ọba Akinolu yẹyẹ Peter Obi, o loun ko fẹẹ rii soju


Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii ti sọ pe Ọba ilu Eko, Ọba Rilwan Akinolu ti yẹyẹ oludije s'ipo aarẹ orileede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour.
 
Bo tilẹ jẹ pe a ko le f'idi iroyin naa mulẹ titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, sibẹ, wọn ni gbogbo igbesẹ Peter Obi lati ṣabẹwo si Ọba Akinolu lo ja si pabo, l'ọsẹ to kọja.
 
Wọn ni awọn alakoso eto ipolongo idibo fun Peter Obi ni wọn mu iwe lọ si aafin Ọba Akinolu lati rii, ṣugbọn ti wọn ni kabiyesi paṣẹ pe oun ko fẹẹ ri oludije s'ipo aarẹ miran to kọja Tinubu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI