A maa ka gbogbo awon to wa ninu igbo Sambisa – Ajọ eleto ikaniyan, NPC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, March 19, 2023

A maa ka gbogbo awon to wa ninu igbo Sambisa – Ajọ eleto ikaniyan, NPC


Ajọ eleto ikaniyan lorileede Naijiria, National Population Census ti sọ pe gbogbo awọn olugbe abule Sambisa ati agbegbe rẹ l’awọn yoo ka ninu eto ikaniyan ati ile to n bọ lọna l’oṣu karun-un, ọdun 2023 yii.
 
Bakan naa ni ajọ ọhun tun sọ pe eto ikaniyan t'ọdun yii ko ni nnkan ṣe pẹlu ọrọ oṣelu, tabi ọrọ ẹlẹyamẹya, nitori pe gbogbo eto lo ti pari lati rii pe ohun gbogbo lọ bo ṣe gbọdọ lọ.
 
Kọmiṣanna fọrọ eto ikaniyan, NPC n’ipinlẹ Ogun, Ọnarebu Arabinrin Ṣeyi Aderinokun lo sọrọ naa nibi idanilẹkọọ ọlọjọ-kan ti ajọ naa gbe kalẹ f’awọn akọroyin n’ipinlẹ Ogun, niluu Abẹokuta l’Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, to kọja yii.

Aderinokun sọ pe eto ikaniyan yii yoo waye ni ibamu pẹlu ofin, ati fun ijọba orileede yii lati ṣe awọn ojuṣe wọn lori agbekalẹ idagbasoke ati eto ọrọ aje orileede yii.

Aderinokun, ẹni ti Ọgbẹni Oluṣọla Adelẹyẹ ṣoju fun jẹ ko di mimọ pe awọn ẹrọ igbalode ti yoo jẹ ki iṣẹ rọrun l’awọn ti pese silẹ, eyi ti ko nii dabi ẹrọ BVAS ti ajọ eleto idibo lo fun idibo to ṣẹṣẹ pari yii, nitori pe ọna igbalode l’awọn fẹẹ gbe ti ọdun yii ka.

Ọtunba Lanre Anifowoṣe to je ọga agba to ti fẹyinti nileeṣẹ NPC ninu ọrọ rẹ sọ pe gbogbo awọn olugbe abule Sambisa ati agbegbe rẹ nibi ti awọn agbebọn sọ di ibudo, paapaa lapa Ariwa orileede Naijiria l’awọn yoo ka ninu eto ikaniyan ati ile to n bọ lọna l’oṣu karun-un, ọdun 2023 yii, lai si idiwọ. 

Bẹẹ lo ni gbogbo ibi ti awọn eeyan n lero wi pe yoo jẹ idiwọ ati ipenija lati ka awọn to wa nibẹ, yala lapa Ariwa tabi Ila-Oorun orileede yii lawọn yoo ṣiṣẹ de, nitori pe awọn ti pari gbogbo ohun to nilo lati ṣe, nipa iranlọwọ ijọba apapọ.


Anifowoṣe sọ pe awọn ti lọ sibẹ lati ba awọn to wa nibẹ sọrọ, ti wọn si ti jẹ ko ye gbogbo awọn agbebọn to wa nibẹ lati jẹ ki wọn mọ pataki eto ikaniyan, paapaa eyi to fẹẹ waye lọdun yii.

Ninu idanilẹkọọ tiẹ, Ọgbẹni Fọlami Muka to jẹ alakoso nileeṣẹ naa, nigba to n sọrọ lori itan bi eto ikaniyan ṣe bẹrẹ lorileede Naijiria ati ilana rẹ sọ pe ilana ti awọn oyinbo gbe kalẹ wi pe ọdun mẹwaa-mẹwaa ni ki eto ikaniyan maa waye ni Naijiria tẹle tẹlẹ ko to di pe nnkan yiwọ, ṣugbọn to sọ pe o ṣeni laani pe eto ọhun ti wa di ọdun mẹtadinlogun ni Naijiria bayii.

Nigba to n sọrọ lori awọn ipenija to ti de ba eto ikaniyan sẹyin lorileede yii, sọ pe pupọ awọn eto ikaniyan to ti waye kọja lọ, lo ni awuyewuye ninu, pẹlu bi wọn ṣe ki ọrọ oṣelu bọ ọ, to si ni t’ọdun yii yoo yatọ si ti atẹyinwa.

O ni ṣaaju eto ikaniyan to waye kẹyin ni Naijiria lọdun 2006, ọdun 1991 ni eto ikaniyan ti waye kẹyin, eyi to lo jẹ ọdun mẹẹdogun. Ṣugbọn ọkunrin naa jẹ ko di mimọ pe gbogbo eto lo ti pari patapata lati rii eto ikaniyan ọdun yii lọ bo ṣe yẹ ko lọ, lai si awuyewuye bi awọn eyi to ti waye kẹyin.

Ninu ọrọ tiẹ, Ọgbẹni Alayaki P.O sọ pe gbogbo awọn ti yoo ṣiṣẹ lori papa bi oṣiṣẹ ajọ NPC, akọroyin, awakọ ati bẹẹbẹẹlọ ni wọn yoo ka patapata lai jẹ pe wọn wa nile pẹlu awọn mọlẹbi wọn, nitori pe gbogbo eto naa lawọn ti ṣe silẹ. 

O ni awọn ti pese ẹrọ igbalode ti yoo jẹ ki iṣẹ kika awọn eeyan ati ile rọrun f'awọn oṣiṣẹ wọn, paapaa ti yoo tun maa gbe e sori ikanni ayelujara lai fi akoko ṣofo.

Lakotan, o fi kun ọrọ rẹ pe ọsẹ meji ṣaaju ki eto ikaniyan bẹrẹ lawọn yoo ti lọ kaakiri lati ka gbogbo ile to wa lorileede yii patapata, lati mọ iye to jẹ. O tun ni pataki ikaniyan ati ile ni lati mọ ohun ti ijọba fẹẹ ṣe lori idagbasoke, paapaa nipa eto ọrọ aje.

Alakoso ileeṣẹ tẹlifiṣan ijọba apapọ, Arabinrin Funmi Wakama wa rọ awọn akọroyin lati ṣiṣẹ papọ pẹlu ajọ eleto ikaniyan nipa gbigbe awọn iroyin otitọ jade, ki wọn si yatọ si iroyin ofege.

Wakama ni awọn alakoso NPC ṣetan lati fun akọroyin ni ohun gbogbo ti wọn ba n fẹ lati le jẹ ki wọn gbe iroyin otitọ jade nipa eto ikaniyan to n bọ. Bẹẹ lo tun rọ wọn lati ma ṣe kanju nipa kikọ iroyin, eyi to sọ pe o maa n fa iroyin ofege ati iroyin ẹlẹjẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI