Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti tẹ baba agbalagba ẹni ọdun marundinlaadọta kan, Ojo Akerele lori ẹsun ifipabanilopọ, to si ti bẹrẹ sii ka boroboro wi pe iṣẹ eṣu ni, ki wọn foju aanu wo oun.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Funmilayọ Ọdunlami nigba to n f’idi iṣẹlẹ ọhun mulẹ laipẹ yii ṣalaye pe adugbo kan ti wọn n pe ni Idoani, ijọba ibilẹ Ose n’ipinlẹ naa ni iṣẹlẹ ọhun ti waye.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọmọ ọdun mẹwaa ni ọmọdebinrin ti Ojo Akerele f’ipa ba laṣepọ.
Wọn ni niṣe ni Ojo fi ọgọrun-un naira tan ọmọdebinrin naa lọ sinu ile akọku kan to wa lagbegbe ọhun, ko to f’ipa ja ibale rẹ.
Ojo nigba to n jẹwọ ẹṣẹ rẹ sọ pe ọmọdebinrin naa maa n tẹle awọn ọrẹ rẹ wa lati maa gba ọgọrun naira lọwọ oun lojoojumọ, to si jẹ pe owo naa loun fi tan an.
O sọ pe bo ṣe n wa gba owo naa lọwọ oun, loun fi fa oju mọra, ko to di pe oun ri anfaani lati ba a laṣepọ. Bẹẹ lo bẹbẹ pe iṣẹ eṣu ni, ati pe oun ko mọ pe aṣiri maa pada tu sita.
No comments:
Post a Comment