Awọn olori ọja fontẹ lu Dapọ Abiọdun fun saa keji l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, March 9, 2023

Awọn olori ọja fontẹ lu Dapọ Abiọdun fun saa keji l'Ogun


Ẹgbẹ awọn olori ọja kaakiri ipinlẹ Ogun ni wọn ti kede sita wi pe awọn yoo ṣatilẹyin fun Ọmọọba Dapọ Abiọdun lati pada s'ipo gmina lẹẹkeji, pẹlu ileri wi pe awọn fun un ni ibo rẹpẹtẹ.

 
Gbogbo awọn olori ọja kaakiri ijọba ibilẹ ogun to wa n'ipinlẹ naa ni wọn fi erongba wọn han nibi ipade ti wọn ṣe ninu gbọngan atijọ ti Ake to wa niluu Abẹokuta l'Ọjọru, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Nibi ipade oloṣooṣu naa ni wọn ti sọ pe o pọn dandan fun wọn lati dibo fun Dapọ Abiọdun lẹẹkeji, nitori pe awọn nigbagbọ ninu ẹ kọja ohun ti ẹnikẹni le lero.
 
Nigba to n gba ẹnu awọn olori ọlọja naa sọrọ, Arabinrin Yẹmisi Abass to jẹ Iyalọja agba nipinlẹ Ogun sọ pe igba akọkọ ree ti ijọba yoo maa san owo oṣu f'awọn Iyalọja lati maa fi tọju ara wọn.
 
Arabinrin Abass to tun jẹ Iyalọja ilẹ Yewa sọ pe gbogbo ijọba ibilẹ marun-un to wa ni ẹkun Yewa patapata ni wọn ṣetan atilẹyin fun Gomina Dapọ Abiọdun lẹẹkeji, ati pe ibo tawọn ba di fun Abiọdun yoo jẹ ko tẹsiwaju awọn akanṣe iṣẹ to n ṣe lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI