Nnkan de! Ọmọ ọdun mẹrindinlogun fipa ja ibale ọmọ ọdun marun-un l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, March 9, 2023

Nnkan de! Ọmọ ọdun mẹrindinlogun fipa ja ibale ọmọ ọdun marun-un l'Ekoo


Ọmọdekunrin, ọmọ ọdun mẹrindinlogun kan, Tosin Oloyede to fipa ja ibale ọmọ ọdun marun-un niluu Ekoo ti foju ba ile ẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe Ọgba, lori ẹsun ifipabanilopọ.
 
Ile-ẹjọ naa si ti paṣẹ pe ki wọn ṣi lọ fi ọmọ naa pamọ sọgba ẹwọn awọn ọmọde ọkunrin to wa lagbegbe Ọrẹgun, Ikẹja titi di ọjọ kejila, oṣu kẹrin, ọdun 2023 yii.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ọjọ karundinlọgbọn ti awọn ọmọ Naijiria lọ dibo lati yan awọn adari tuntun lorilede yii, ni Tosin lo anfaani ile to da lati fipa ja ibale ọmọ ọdun marun-un ọhun.

Agbefọba Akeem Raji to foju Tosin ba ile ẹjọ, niwaju Onidajọ B. O Oṣusanmi, o ni ọkan lara awọn ọmọ ayalegbe ninu ile ti Tosin n gbe niluu Ikorodu ni ọmọ ọdun marun-un naa.
 
Lara awọn to wa nile ẹjọ naa jẹ ko ye wa pe bi ọmọ ọdun marun ọhun ṣe foju kan Tosin, lo ti bẹrẹ sii sunkun, to si n sa fun un, eyi to ya ọpọ awọn to wa nibẹ lẹnu.

Wọn ni baba ọmọ naa lo dibo lọjọ naa ni, asiko ọhun lo si ri gẹgẹ bi anfaani lati fi ṣiṣẹ buruku naa, lai mọ pe aṣiri maa pada tu sita.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI