Aye o! Ọmọ ọdun mẹtala yinbọn pa ọmọ ọdun mẹta l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, March 11, 2023

Aye o! Ọmọ ọdun mẹtala yinbọn pa ọmọ ọdun mẹta l'Ogun


Bo tilẹ jẹ pe kayeefi nla gba a lọrọ ọmọ ọdun mẹtala kan, Ọpẹ Babalọla ti wọn lo yinbọn pa ọmọ ọdun mẹta, Esther Samuel ṣi n jẹ fun ọpọ awọnn to gbọ, sibẹ, ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ baba agbalagba, ẹni ọdun marundinlaadọta, Sẹmiu Adegẹṣin to ni ibọn ti ọmọ naa lo.
 
Abule kan ti wọn pe ni Kukudi to wa ni Imaṣayi, ipinlẹ Ogun ni iṣẹlẹ ọhun ti waye, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe Sẹmiu lo ki ibọn rẹ pẹlu ọta ninu, to si gbe si ẹyinkule ile, iyẹn nibi ti awọn ọmọde ti maa n ṣere. Wọn ni bo ṣe gbe ibọn naa silẹ, lo jade lọ lai bikita nipa ibọn rẹ.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ni Sẹmiu ko ṣẹṣẹ maa gbe ibọn ọhun silẹ lẹyinkule ile, ṣugbọn ti kii si ọta ibọn ninu ẹ, koda ti wọn lawọn ọmọde maa fi n ṣere, sibẹ, a gbọ pe ko si ọmọ kankan lẹyinkule lakoko to gbe ibọn naa sibẹ.

Wọn ni bo ṣe jade lọ, to fi ibọn rẹ siibẹ, ni awọn ọmọ naa ko ra wọn lọ si ẹyinkule lati ṣere, gẹgẹ bi iṣe wọn. Nibi ti wọn si ti n ṣere naa la gbọ pe Ọpẹ ti lọ gbe ibọn yii, to si doju rẹ kọ ọmọ ọdun mẹta ọhun.

Lojiji lo yinbọn naa, to si ba ọmọ ọdun mẹta yii, iyẹn Esther, tiyẹn si sọda sọrun alakeji loju ẹsẹ.

Awọn to wa nibẹ la gbọ pe wọn pariwo sita, eyi to mu k'awọn ara abule naa sare lọ sibẹ lati wo nnkan to ṣẹlẹ, to si jẹ iyalẹnu nigba ti wọn ri ọmọ ọhun ninu agbara ẹjẹ.
 
Ohun ti a tiẹ gbọ ni pe awọn ara abule gbiyanju lati gbe ọmọ naa lọ si ọsibitu lati wo boya atunṣe ṣi wa, ṣugbọn ti wọn sọ pe aṣọ ko bọmọyẹ mọ, ọmọyẹ ti rin ihooho wọja.
 
Nibẹ ni wọn ti gba teṣan ọlọpaa agbegbe Imaṣayi lọ lati fi to wọn leti, ti awọn yẹn naa si sare gbera lati lọ wo nnkan to ṣẹlẹ.
 
Loju ẹsẹ ni wọn ti ranṣẹ si Sẹmiu nibi to wa lati wa a wo nnkan to fi iwa aibikita rẹ da silẹ, ti awọn ọlọpaa si gbe e lọ teṣan wọn fun ifọrọwanilẹnuwo nipa idi to fi gbe ibọn naa silẹ nibi t'awọn ọmọde wa.
 
Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun,  Frank Mba, nigba to n ba awọn ẹbi ọmọ naa kẹdun, o ṣeleri wi pe awọn yoo tọpinpin iṣẹlẹ naa daadaa, lati rii pe idajọ ododo waye lori ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI