O ma ṣe o! Yinka Ayefẹlẹ padanu ọkan lara awọn sọrọsọrọ ileeṣẹ redio Fresh FM n'Ibadan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, March 11, 2023

O ma ṣe o! Yinka Ayefẹlẹ padanu ọkan lara awọn sọrọsọrọ ileeṣẹ redio Fresh FM n'Ibadan


Iroyin ibanujẹ lo ba gbogbo awọn alaṣẹ ati oṣiṣẹ ileeṣẹ redio Fresh FM to jẹ ti gbajugbaja onkọrin igbagbọ-Juju nni, Ọmọwe Ọlayinka Joel Ayefẹlẹ nigba ti wọn gbọ nipa iku ọkan lara awọn ilu-mọ-ọn-ka sọrọsọrọ wọn, iyẹn Baba Bintin.
 
Ori eto ti oloogbe naa maa n ṣe pẹlu awọn agba sọrọsọrọ meji nni, Ọlalọmi Amọle ati Kọmọlafẹ Ọlaiya ni wọn ti kede iku Baba Bintinlaye laaarọ oni, ọjọ Abamẹta, Satide.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ori eto ọhun ni Baba Bintinlaye n lọ, ko to ṣubu lulẹ loju ọna, to si gbabẹ sọda sọrun alakeji.
 
Lara awọn to ri ọkunrin naa nigba to ṣubu lulẹ lakoko to n fi ẹsẹ rin lọ si ileeṣẹ redio Fresh FM naa la gbọ pe wọn sare gbe e lọ si ọsibitu UCH lati doola ẹmi ẹ.
 
Ibẹ la gbọ pe wọn ti jẹ ko di mimọ pe ẹpa ko boro mọ, ẹlẹmi ti gba a.
 
Kọmọlafẹ Ọlaiya ati ẹnikeji rẹ, Ọlalọmi Amọle ni wọn kede iku Baba Bintinlaye lori eto wọn, Oyin Ado laaarọ oni.
 
Ninu ohun ọkunrin kan ti wọn gbe sita, wọn sọ pe ibi to ṣubu si ni wọn ti rii, ko to di pe wọn sare gbe e lọ si ọsibitu, ṣugbọn to ni o ṣeni laanu wi pe ọkunrin naa ti dakẹ.
 
Odu ni Baba Bintinlaye, kii ṣaimọ foloko, iyẹn fawọn ololufẹ ileeṣẹ redio Freshm FM lorileede Naijiria. Ede Ijẹṣha si lọkunrin naa fi maa n sọrọ nigba to ba n ṣeto lori Oyin Ado.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI