Bisikiiti la fi n tan awọon ọmọde ka to ji wọn gbe - Ọmọ-ọdun mẹrindinlogun jẹwọ l'Ondo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, March 3, 2023

Bisikiiti la fi n tan awọon ọmọde ka to ji wọn gbe - Ọmọ-ọdun mẹrindinlogun jẹwọ l'Ondo


Ọmọ ọdun mẹrindinlogun kan, Lekan Mustapha ti wọn mu lori ẹsun ijinigbe n'ipinlẹ Ondo ti jẹwọ niwaju ile ẹjọ Majisireeti to wa niluu Akurẹ ti sọ pe bisikiiti l'oun pẹlu awọn isọngbe oun fi maa n tan awọn ọmọ kekeeke lati fi ji wọn gbe.
 
Lekan ati ọrẹ rẹ kan, Zulum Yisa lọwọ ẹṣọ aabo ilẹ Yoruba, Amọtẹkun tẹ laipẹ yii, ti wọn si foju wọn ba ile ẹjọ lori ẹsun ijinigbe lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlọgbọn,oṣu kinni, ọdun yii.
 
Nigba to n foju ba ile ẹjọ, Lekan sọ pe bisikiiti lawọon fi maa n tan awọn ọmọ kekeeke, pẹlu oruka abami, to lawọn ti ji awọn ọmọde ti ko din ni mẹsan.
 
Lekan sọ pe ọdọ Aafa kan lawọn n ko awọn ọmọ ti wọn ba jigbe lọ niluu Ikorodu, ipinlẹ Ekoo.
 
Agbegbe kan ti wọn pe ni Ọka Akoko, Akoko North-West lọwọ ti tẹ awọn mejeeji yii, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
Agbefọba, O.F Akeredolu, nigba to n fẹsun kan awọn mejeeji nile ẹjọ, o ni awọn mejeeji ko niṣẹ meji ti wọno yan laayo, to kọja ijinigbe, to si ni wọn ti jẹwọ pe ọmọ kekeeke lawọn fẹran lati maa jigbe.
 
Lekan ninu ọrọ rẹ sọ pe Yisa loun n ṣiṣẹ fun, ẹni toun naa n ṣiṣẹ pẹlu awọn kan niluu Eko. O ni Aafa lo f'awọn ni oruka buruku lati maa fi gba awọn ọmọ naa, eyi ti yoo jẹ ki wọno tẹle wọn.
 
Ninu ọrọ rẹ, o ni “Ọdọ Yisa ni mo n gbe latigba ti mo ti padanu awọn obi mi, ki n le ri aye gbe. Ilu Ilọrin la si ti jọ wa s'ibi.
 
"Nigbakugba ti a ba fẹẹ ji eeyan gbe, Yisa maa n fun mi ni bisikiiti lati fi tan awọn ọmọ ti a ba fẹẹ jigbe, bi wọn ba si ti gba a, wọn maa tẹle mi lọ sọdọ Yisa. Ti wọn ba si ti de ọdọ ẹ, o maa fi oruka gba wọn, ti wọn ko si ni mọ ohun ti wọn n ṣe mọ.
 
"Ọdọ Aafa to n gbe niluu Ikorodu la maa n fi awọn ọmọ naa ranṣẹ si. Ọmọ mẹsan la ti jigbe.”
 
Ninu ọrọ Onidajọ Damilọla Ṣekoni, o paṣẹ pe ki wọn ṣi lọ fi Yisa pamọ sọgba ẹwọn, bẹẹ lo paṣẹ pe ki wọn lọ fi Lekan pamọ sile awọn ọmọ alaigbọnran, nigba ti wọn yoo maa reti amọran lati ọdọ DPP.
 
O wa sun igbẹjọ miran siwaju di ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹta, ọdun 2023.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI