Nitori bi wọn ṣe kede Tinubu, ipinlẹ mẹfa gbe ijọba apapọ lọ sile ẹjọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, March 3, 2023

Nitori bi wọn ṣe kede Tinubu, ipinlẹ mẹfa gbe ijọba apapọ lọ sile ẹjọ


Ipinlẹ mẹfa ọtọọtọ lorileede Naijiria la gbọ pe wọn ti gbe ijọba apapọ orileede yii lọ sile ẹjọ, lori bi wọn ṣe kede oludije s'po aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Bọla Ahmẹd Tinubu gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori.
 
Awọn ipinlẹ naa ni, Adamawa, Akwa-Ibom, Bayelsa, Delta, Ẹdo ati Ṣokoto. Ile ẹjọ agba orileede yii la gbọ pe wọn wọ ijọba apapọ lọ lori eto idibo ọjọ karundinlọgbọn, oṣu keji ti ajọ INEC kede.
 
Lara awọn ẹbẹ ti awọn ipinlẹ naa n bẹ ile ẹjọ ni lati wọgile idibo to gbe Tinubu wọle gẹgẹ bi aarẹ tuntun Naijiria, nitori pe ajọ eleto idibo, INEC ko tẹle ilana eto idibo tuntun to wa nita.
 
Wọn ni bi ajọ eleto idibo ko ṣe gbe awọn esi idibo lawọn ibudo idibo 176,974 to wa lorileede yii sori ikanni ayelujara ṣaaju akoko ti wọn kede, eyi ni wọnn lo tako ilana ofin idibo, iyẹn 'electoral act'.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI