Dapọ Abiọdun di gomina lẹẹkeji l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 20, 2023

Dapọ Abiọdun di gomina lẹẹkeji l'Ogun


Ajọ eleto idibo nipinlẹ Ogun ti kede Ọmọọba Dapọ Abiọdun gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu eto idibo gomina to waye l'opin ọsẹ to kọja yii.
 
Ọjọgbọn Kayọde Adebọwale to jẹ Giwa fasiti ilu Ibadan lo kede Ọmọọba Dapọ Abiọdun gẹgẹ bi ẹni to bori ninu eto idibo gomina ipinlẹ Ogun.
 
Agba Ọmọwe naa ni Dapọ Abiọdun ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC bori pẹlu ibo 276,298, nigba ti Ọladipupọ Adebutu lati inu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP tẹle e lẹyin pẹlu ibo 262,383.
 
Nigba to n kede ẹni to ṣe ipo kẹta, o ni Biyi Ọtẹgbẹyẹ lati inu ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC lo ni ibo 94,754.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI