Wọn ni Damọla Ọlatunji ko jade nile, nitori obinrin miran to fun loyun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, March 21, 2023

Wọn ni Damọla Ọlatunji ko jade nile, nitori obinrin miran to fun loyun


Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii la ko tii le fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, ṣugbọn iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ sọ pe gbajugbaja oṣere tiata nni, Damọla Ọlatunji lo ti ko ẹru jade kuro nile toun pẹlu iyawo ẹ, Bukọla Arugba n gbe pẹlu awọn ọmọ wọn.

Oniroyin ori ayelujara to maa n tu aṣiri awọn oṣere, iyẹn Gistlover lo gbe iroyin naa sita laipẹ yii.

Gistlover sọ pe Damọla Ọlatunji fun obinrin kan to n yan ni ale loyun, aṣiri naa si tu si iyawo rẹ, Arugba lọwọ.

Ija nla lo sọ pe o ṣẹlẹ, to fi ni Damọla ti ko ẹru rẹ kuro nile.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI