Ẹ ma ṣe dibo fun oludije sipo gomina to ba wa lati Yewa, ko tii to asiko fun ọmọ Yewa lati di gomina ipinlẹ Ogun - Ọba Olugbenle pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 6, 2023

Ẹ ma ṣe dibo fun oludije sipo gomina to ba wa lati Yewa, ko tii to asiko fun ọmọ Yewa lati di gomina ipinlẹ Ogun - Ọba Olugbenle pariwo sita


Olu Ilaro ati olori ọba ilẹ Yewa lapapọ, Ọba Kẹhinde Gbadewọle Olugbenle ti sọ pe ki ẹnikẹni ma ṣe dibo fun oludije sipo gomina to ba jade lati ẹkun Yewa, nitori pe ko tii to asiko fun wọn lati di gomina.

Kabiyesi naa sọ pe ki awọn ọmọ ati olugbe ilẹ Yewa lapapọ dibo fun Gomina Dapọ Abiọdun lati pada sipo naa lẹẹkeji, ki itẹsiwaju ati idagbasoke le ba agbegbe naa.

Ọba Olugbenle lo sọrọ naa lasiko to n gba gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun lalejo ni aafin rẹ lopin ọsẹ to kọja yii.

Gẹgẹ bi Kabiyesi naa ṣe sọ, o ni idibo gomina to n bọ lọjọ kọkanla, oṣu kẹta, ọdun ti a wa yii, ki wọn ma ṣe jẹ ki wọn fi ọmọ onilẹ tan wọn jẹ, wi pe Yewa lo kan.

O ni itẹsiwaju idagbasoke ni ipinlẹ Ogun, paapaa ilẹ Yewa nilo lakoko yii, ati pe ẹnikan ṣoṣo to le ṣe e ni Ijọba to wa lori aleefa lọwọlọwọ.

Siwaju sii lo sọ pe idibo to n bọ yii kii ṣe ti oṣelu, bi ko ṣe ohun tawọn eeyan n fi oju ri.

Nibẹ lo ti parọwa si gbogbo ọmọ Yewa lati ma ṣe tẹwọ gba oludije ti gomina ana nipinlẹ Ogun n ṣagbatẹru, ẹni to sọ pe ko pari awọn akanṣe iṣẹ to dawọle kaakiri ilẹ Yewa fun ọdun mẹjọ to fi wa lori iṣakoso.

Bakan naa lo sọ didi ibo fun Dapọ Abiọdun kii ṣe ọrọ oṣelu, bi ko ṣe fun itẹsiwaju ilẹ Yewa, eyi ti awọn ti fi oju ri labẹ iṣakoso rẹ.

Nibẹ lo ti ti rawọ ẹbẹ si Gomina Abiọdun lati da oju irin Idọdọ si Ifọ pada, ko ba a le mu itẹsiwaju ba eto ọrọ aje ilẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI