O tan! Oloye ẹgbẹ PDP miran tun lọ darapọ mọ APC ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, March 7, 2023

O tan! Oloye ẹgbẹ PDP miran tun lọ darapọ mọ APC ni Kwara


Ọkan gboogi lara awọn oloye ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP n'ipinlẹ Kwara, Kọmureedi Yusuf Adeṣhina Abubakar ni iroyin ti fi to wa leti pe o ti fẹgbẹ naa silẹ bayii, o si lọ darapọ mọ ẹgbẹ miran.
 
AWIKONKO gbọ pe ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ni Kọmureedi Abubakar lọ darapọ mọ, pẹlu ileri wi pe oun yoo ṣagbatẹru ipolongo ibo fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lati pada s'ipo naa lẹẹkeji.

Oludamọran pataki lori ọrọ to nii ṣe pẹlu ofin, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni Legal Adviser ni wọọdu Oke-Ogun, ijọba ibilẹ Guusu Ilọrin ni wọn pe Abubakar.
 
Wọn l'ọkunrin naa sọ pe oun ko le tẹsiwaju mọ gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP, nitori pe oju oun ti la si otitọ, ati pe oun nifẹẹ idagbasoke ati ilọsiwaju ipinlẹ naa, lo fa a toun fi lọ faramọ APC.
 
 
Pẹlu lẹta ni wọn sọ pe Abubakar fi kede sita wi pe oun ko ṣẹgbẹ PDP mọ, bi ko ṣe APC, koda, o tun loun faramọ bi Gomina AbdulRazaq ṣe n ṣakoso ipinlẹ aa lai fi ti ọrọ ẹlẹyamẹya ṣe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI