Ẹgbẹ oṣelu Labour fontẹ lu Dapọ Abiọdun lati di gomina ipinlẹ Ogun lẹẹkeji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, March 11, 2023

Ẹgbẹ oṣelu Labour fontẹ lu Dapọ Abiọdun lati di gomina ipinlẹ Ogun lẹẹkeji


Ẹgbẹ oṣelu Labour nipinlẹ Ogun ti kede sita wi pe awọn ti fontẹ lu Gomina Dapọ Abiọdun lati dije du ipo gomina fun saa keji, pẹlu ileri wi pe awọn yoo ṣatilẹyin fun un lakoko eto idibo.
 
Igbimọ fidihẹ to n ṣakoso ẹgbẹ naa la gbọ pe wọn lọ fa ọwọ Abiọdun soke ni ọfiisi rẹ to wa ni Oke-Mọsan niluu Abẹokuta, lati sọ pe awọn wa lẹyin rẹ digbi fun saa keji.
 
Wọn lawọn nifẹẹ si awọn ayipada rere to ti n de ba ipinlẹ naa latigba to ti gba iṣakoso lọdun 2019.
 
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI