Sanwo-Olu wọgile ipolongo idibo rẹ fọjọ mẹta, o tun l'awọn oṣiṣẹ Ekoo ko nii ṣiṣẹ bii tẹlẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, March 10, 2023

Sanwo-Olu wọgile ipolongo idibo rẹ fọjọ mẹta, o tun l'awọn oṣiṣẹ Ekoo ko nii ṣiṣẹ bii tẹlẹ


Gomina Babajide Sanwo-Olu tipinlẹ Ekoo ti kede isinmi ọlọjọ mẹta lati fi kẹdun awọn to padanu ẹmi wọn, ati awọn to farapa yannayanna ninu ijamba ọkọ reluwee ati ọkọ akeroo t'ijọba ipinlẹ naa, eyi ti ṣẹlẹ l'Ọjọbọ, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Sanwo-Olu sọ pe ibanujẹ nla lo jẹ foun nigba toun gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun, paapaa lakoko toun ṣabẹwo sibi iṣẹlẹ naa, ati boun tun ṣe ri b'awọn eeyan ṣe farapa kọja sisọ.
 
O ni iroyin ibanujẹ nla ni, toun si gbọdọ ja asia orileede Naijiria ati ipinlẹ Ekoo wa si agbede meji lati fi kẹdun awọn to kagbako ijamba naa to ṣẹlẹ lojiji.
 
Sanwo-Olu ni oun ti wọgile ipolongo idibo oun fun ọjọ mẹta.

Awọn mẹfa la gbọ pe wọn padanu ẹmi wọn ninu ijamba naa, nigba ti awọn mọkandinlọgọrin si farapa yannayanna.
 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI