Ijọba Kwara bẹrẹ sisan owo ifẹhinti awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, March 4, 2023

Ijọba Kwara bẹrẹ sisan owo ifẹhinti awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ gomina wọn, AbdulRahman AbdulRazaq ti bu ọwọ lu owo ifẹhinti fawọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ kaakiri ipinlẹ naa.

Awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ ti wọn fẹyinti laaarin oṣu kinni si oṣu karun-un, ọdun 2011 ni a gbọ pe ijọba fẹẹ da lọdun.

Bakan naa ni wọn sọ pe awọn oṣiṣẹ fẹyinti lọdun 2009 si 2010, ti wọn ko tii gba iwe sọwedowo wọn ni ki wọn lọ si ileeṣẹ to n bojuto ọrọ owo ifẹyinti lati gba a.

Ninu atẹjade ti akọwe ileeṣẹ to n ri sọrọ owo ifẹyinti naa, Ọgbẹni Oyelọwọ Sumaila fi sita, eyi ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ lo si ṣalaye pe ki gbogbo awọn ti ọrọ naa kan mu awọn iwe idanimọ to yẹ dani bi wọn ba n bọ lọdọ wọn lati le fidi otitọ mu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI