Yoruba lo ni ilu Ekoo, ẹ dẹkun sisọ pe Ekoo kii ṣe ilẹ baba ẹnikan - Yul Edochie - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, March 5, 2023

Yoruba lo ni ilu Ekoo, ẹ dẹkun sisọ pe Ekoo kii ṣe ilẹ baba ẹnikan - Yul Edochie


Gbajugbaja oṣere tiata oloyinbo nni, Yul Edochie ti sọ pe ki awọn eeyan dẹkun lati maa da aṣa wi pe Ekoo kii ṣe ilẹ baba ẹnikan, o ni awọn Yoruba lo ni Ekoo, kii ṣe gbogbo Naijiria.

Yul Edochie lo sọrọ naa lori ikanni ayelujara ti Insitagiraamu rẹ lọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii, to si ni awọn Yoruba maa n gba awọn ẹya miran mọra pẹlu ifẹ ati alaafia.

Bakan naa lo tun sọ pe kii ṣe ahesọ wi pe awọn ẹya Ibo naa ti da si idagbasoke eto ọrọ aje ipinlẹ Ekoo.

Ogbontarigi oṣerekunrin naa sọ pe lati ọdun 2011 toun ti n gbe niluu Ekoo, titi toun fi kọ ile toun sibẹ, o ni ko si iwa ikorira tabi iwa ẹlẹyamẹya nipinlẹ naa, bi ko ṣe pe ifẹ ni wọn fi n ba wọn lo.
 
“Ọdun 2011 ni mo ti n gbe niluu Ekoo. Mo kọ ile mi siluu Ekoo.

“Ko si igba kankan ti mo ni iriri ikorira tabi ikọsilẹ lọdọ awọn Yoruba.

“Nigbakugba ti awọn ọmọ Yoruba ba pade mi loju ọna, wọn maa n kora jọ lati ki mi, ifẹ si ni wọn fi n ṣe e ni gbogbo igba. Ọrọ ti wọn si n sọ kaakiri wi pe Ekoo kii ṣe ilẹ baba ẹnikan kii ṣe otitọ.

“Ipinlẹ Yoruba ni Ekoo wa nilẹ Yoruba. Ẹyin naa ẹ kan ro o wo ki ẹnikan sọ pe Anambra kii ṣe ilẹ baba ẹnikan, ọrọ rirun ni. Ilẹ Igbo ni Anambra wa. Ẹ ko le wa sori ilẹ onilẹ lati wa maa sọ pe kii ṣe ilẹ baba ẹnikan, ẹyin lẹ n wa wahala.

“Ko sẹni to le sọ pe awọn Igbo ko ni ipa ninu idagbasoe ipinlẹ Ekoo. Awọn ẹya miran naa ti ko ipa ti wọn pẹlu. Ati pe awọn ọmọ Yoruba naa n gba awọn eeyan mọra gidigidi. Iyẹn ko wa yẹ ka wa pa otitọ ti lati maa sọ pe Ekoo kii ṣe ilẹ baba ẹnikan, ilẹ Yoruba ni Ekoo. A ko le maa ba awọn ẹni ẹlẹni du ilẹ baba wọn. Ẹ jẹ ka pa ọrọ ẹlẹyamẹya ko to o pa wa.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI