Ijọba Kwara buwọ lu ẹrọ amunawa tuntun marun-un miran fawọn araalu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, March 4, 2023

Ijọba Kwara buwọ lu ẹrọ amunawa tuntun marun-un miran fawọn araalu


Lojuna lati dẹkun idakureku ina mọnamọna, ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina Abdurahman AbdulRazaq ti buwọ lu ẹrọ amunawa tuntun marun-un miran fawọn araalu.

Kọmiṣanna f'ọrọ eto ina, Ọnarebu Abdulwahab Fẹmi Agbaje lo sọ eyi di mimọ l'Ọbọbọ tii ṣe Tọsidee, ọsẹ yii, to si ni awọn agbegbe ti yoo jẹ anfaani nla yii ti bọ s'aye tuntun.

Lara awijare agbegbe ti a gbọ pe wọn yoo gba awọn ẹrọ amunawa tuntun naa ni Oke-Odo niluu Erin-Ile to wa nijọba ibilẹ Oyun;  Ile iwosan ijọba tiluu Ọffa; Obbo Ile to wa lagbegbe Palace, ijọba ibilẹ Ekiti; Oke-Ayewu to wa ni Shao, ijọba ibilẹ Moro, ati As-Sunnah Kutashi, Tanke Oke-Odo, ijọba ibilẹ Ilorin South.

Eyii lo tun waye lẹyin ti iṣakoso to wa nita paṣẹ pe ki wọn lọ ṣe awọn ina mọnamọna to n lo oorun (Solar), eyi ti ko din ni irinwo kaakiri adugbo to wa nijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa ni ipinlẹ ọhun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI