O ma ṣe o! Abdullahi, ọmọ Sanni Abacha toju oorun de oju iku - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, March 4, 2023

O ma ṣe o! Abdullahi, ọmọ Sanni Abacha toju oorun de oju iku


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, inu iyalẹnu ibanujẹ l'awọn mọlẹbi olori orile-ede Naijiria tẹlẹ ri, Oloogbe Ibrahim Sanni Abacha wa, lori bi awọn ninu awọn ọmọ rẹ, Abdullahi Abacha ṣe ku lojiji.

Ko si nǹkan meji to n jẹ kayeefi nipa iku Abdullahi to kọja bo ṣe toju oorun de oju iku, ti ko si tii sẹni to le sọ pato ohun to fa sababi iku naa.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ṣe sọ, wọn ni ile ti Abdullahi n gbe niluu Abuja, eyi to wa lopopona Nelson Mandella lo dakẹ si ni oru mọju

Ọpọ awọn eeyan ni wọn sọ pe wọn ṣi ri Abdullahi ṣaaju ọjọ to maa fi aye silẹ, ti wọn si ni digbi ni ara rẹ ya, ko si nnkan to ṣe e, bẹẹ ni ko fi apẹẹrẹ aisan kankan han.


AWIKONKO gbọ pe Abdullahi, ẹni ọdun mẹtadinlogoji naa sun lalẹ ni, to si jẹ pe nigba ti gbogbo awọn to sun ji saye, ajule ọrun loun ti ba ara rẹ.

Ipo kẹjọ ni wọn sọ pe Abdullahi wa ninu awọn ọmọ ti baba rẹ, Oloogbe Sanni Abacha fi silẹ saye lọ.

Ẹgbọn oloogbe naa, Fatimah-Gumsu Abacha-Buni to jẹ iyawo gomina ipinlẹ Yobe, lo kede ọrọ naa lori ikanni abẹyẹfo (twitter) rẹ;

Ninu ohun to kọ sibẹ ni pe;
‘'Inna lillahi wa inna ilaehi rajiun (Ohun to daju ni pe ọdọ Allah ni a ti wa, ọdọ rẹ naa ni a oo pada si). Mo padanu aburo mi, Abdullahi Sani Abacha. Oju oorun lo ti de oju iku. Ki Ọlọrun Allah foju pa aṣiṣe rẹ rẹ, ko si tẹ ẹ si Aljanah onidẹra. Ẹ jọwọ, ẹ ba mi ranti rẹ ninu adura."

Nnkan bi aago mẹrin irọlẹ oni, ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrin, oṣu yii, ni wọn sinku Oloogbe naa ni mọṣalaṣi nla to wa niluu Abuja.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI