Mo ti bẹ Yẹni Kuti o - Folukẹ Daramọla pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, March 31, 2023

Mo ti bẹ Yẹni Kuti o - Folukẹ Daramọla pariwo sita


Gbajugbaja oṣerebinrin nni, Foluke Daramọla ti sọ pe oun ti bẹ Yẹni Kuti, toun naa jẹ ogbontarigi sọrọsọrọ ori redio lori ẹsun to fi kan oun, ati pe ko s'ija mọ laaarin awọn.
 
Daramọla lo sọ pe oun ti bẹ Yẹni lori ẹsun to fi kan oun wi pe oun sọrọ abuku sii lọdun meloo kan sẹyin.
 
Yẹni Kuti lo sọ pe lọdun meloo kan sẹni ni Folukẹ Daramọla ko bọwọ f'ọun nita gbangba, to si ni iṣẹlẹ naa dun oun gidigidi.
 
Loju ẹsẹ ni Daramọla ti sọ pe otitọ ọrọ ni Yẹni sọ, ṣugbọn o ni bo ṣe jẹ nigba naa, ati pe oun ti tọrọ aforiji lọwọ ẹ.
 
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Mo wa si ori ayelujara lati sọrọ kekere yii, nitori pe ninu awọn ọrẹ mi ati awọn alabaṣiṣẹpọ mi ti pe mi si akiyesi ifọrọwerọ ti Anti Yẹni Kuti ṣe, iyẹn 'Your View' wipe mi o bọwọ fun un lọdun diẹ sẹyin
 
"Mo n ṣe yi nitori pe ita gbangba lo ti fẹsun naa kan mi, bo tilẹ jẹ pe mo ti ba a sọrọ labẹlẹ.
 
"Wi pe mi o ni bọwọ fun awọn ti a jọ jẹ ẹgbẹ ko si ninu iwa mi, ki a ma ṣẹṣẹ wa sọ pe awọn to dagba ju mi lọ, ati pe Anti Yẹmi jẹ ẹni kan ti mo to si ipo giga nitori pe ọga ni wọn jẹ si mi lẹnu iṣẹ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI