Bi ẹ fẹ, bi ẹ kọ, mi o ni dẹkun ijo jijo - Adeleke sọ f'awọn to n bu ẹnu atẹ luu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, March 29, 2023

Bi ẹ fẹ, bi ẹ kọ, mi o ni dẹkun ijo jijo - Adeleke sọ f'awọn to n bu ẹnu atẹ luu


Gomina Ademọla Adeleke t'ipinlẹ Ọṣun ti sọ pe gbogbo erongba oun lati kekere ni lati jẹ amuludun, koun si maa da awọn eyan laraya, fun idi eyi, o ni kawọn to ro pe oun dẹkun ijo jijo lọ jokoo jẹ, nitori pe ala ti ko le ṣe rara ni.
 
Adeleke ni baba oun ni ko jẹ ki ipinnu oun wa si imuṣẹ, nitori pe to ni koun gbajumọ ọrọ eto ẹkọ to ṣe pataki.
 
Gomina Adeleke lo sọrọ naa laipẹ yii ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin kan ti wọn pe ni News Central Africa.
 
Nibẹ lo ti sọ pe 
“Orin maa n je ki n wa daadaa, o maa n mu ara mi ya lọpọlọpọ. Mo fẹran orin gan-an. Mo si fẹran ijo jijo. Koda, agboole amuludun lo yẹ ki n wa. Lakoko ti a n dagba, baba wa lero wi pe o yẹ ka di dọkita tabi amofin; a ni lati lọ sileewe.”
 
O ni lakoko toun n kẹkọọ lọwọ nilẹ Amẹrika, oun lọ si idije ijo jijo, toun si yege pẹlu ọpọ owo dọla toun gba gẹgẹ bi ẹbun.
 
“Ijo ṣi wa lara mi. Mi o nigbagbọ pe nitori pe mo ti di gomina, tabi pe nigba ti mo wa n'ipo Sẹnetọ, o yẹ ki n dẹkun ijo jijo. Nigba ti a ba ni ipade tabi apẹjọ ariya, awọn eeyan maa n dide.”
 
Nibẹ lo ti ilọ f'awọn to n bu ẹnu atẹ luu lati dẹkun lati maa ṣakoso aye rẹ, nitori pe ohun gbogbo ni asiko wa fun, to fi mọ ijo.
 
Bakan naa lo sọ pe ijo jijo ko le dẹkun awọn ojuṣe oun gẹgẹ bii gomina.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI