Muhammẹd, ọmọ ọdun mejilelogun gun ẹni to n ba a du ololufẹ pa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, March 9, 2023

Muhammẹd, ọmọ ọdun mejilelogun gun ẹni to n ba a du ololufẹ pa


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Adamawa ti tẹ gendekunrin ọmọ ọdun mejilelogun kan to yan iṣẹ Telọ laayo, Muhammed Bala lori ẹsun wi pe o gun ẹni to n ba a du ololufẹ rẹ pa.
 
Bala ni iroyin fi to wa leti pe o n yan ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹtadinlogun kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Maryam Mohammed laayo 
 
Adugbo kan naa la gbọ pe Bala, Maryam ati Bakura ti Bala gun pa n gbe nijọba ibilẹ Madagali, ipinlẹ naa.
 
Wọn ni nigba ti Bala ṣakiyesi pe Bakura n ba oun du obinrin, lo mu ko fibinu gun un lọrun pa, to si tun duro tii pe oun gbọdọ rii pe o ba Ọlọrun lalejo.

O ni ọdun kẹta ree, toun ti kẹnu ifẹ si Maryam, ẹni to loun n wo gẹgẹ bi iyawo ile oun lọjọ iwaju
 
Nigba to n fidi rẹ mulẹ, alukoro ọlọpaa ipinlẹ naa, Suleiman Nguroje sọ pe Bala loun ti fọpọ igba kilọ fun oloogbe naa lati dẹyin lẹyin ololufẹ oun, ṣugbọn ti ko gbọ, to si ni idi niyẹn toun fi gun un pa.
 
A gbọ pe niṣe ni ọrọ yiwọ nigba ti awọn mejeeji pade nile Maryam lọjọ kẹẹdogun, oṣu keji, ọdun yii, ti wọn si bẹrẹ ija. Ibi ti wọn ti n ja ni Bala ti fa ọbẹ yọ, to si gun un pa.
 
Nguroje ti wa fidi rẹ mulẹ pe ọmọkunrin naa ti wa lọgba awọn, nibi to ti n ṣalaye ọrọ rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI