Gbajugbaja onkọrin Afro nni, Ṣeun Kuti ti darapọ mọ awọn to n fa ariyanjiyan nipa ẹya to ni ilu Ekoo, to si ni kii ṣe ẹya Yoruba lo ni ilu Ekoo.
Ṣeun Kuti to jẹ ọmọ olorin agbaye nni to ti doloogbe, Fẹla Anikulapo Kuti lo sọrọ naa lori ikanni ayelujara rẹ laipẹ yii, to si ni ki awọn eeyan yee sọ phun ti wọn ko mọ.
O ni awọn ẹya Yoruba kọ lo ni iluu Ekoo, bẹẹ si ni Ekoo kii ṣe ilẹ baba ẹnikẹni, bi ko ṣe ibudo imunilẹru fawọn ara Yuroopu (European Satallite Slave Port).
Bẹ o ba gbagbe, ariyanjiyan yii lo bẹrẹ lopin ọsẹ to kọja lọ lọhun, nigba ti oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi jawe olubori ni ipinlẹ Ekoo.
B'awọn kan si ṣe n sọ pe Ekoo kii ṣe ilẹ baba ẹnikan, bẹẹ l'awọn miran n sọ pe Yoruba lo ni Ekoo.
Gbajumọ oṣere tiata nni, Yul Edochie naa sọ erongba tiẹ wi pe ilẹ Yoruba lo ni Ekoo, ki awọn eeyan si dẹkun lati maa sọ pe Ekoo kii ṣe ilẹ baba ẹnikan.
Ṣeun Kuti ninu ọrọ rẹ sọ pe ki awọn eeyan sunmọ itan daadaa lati mọ bi nnkan ṣe n lọ, dipo ki wọn maa sọ isọkusọ lẹnu kaakiri.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe
"Ekoo kii ṣe ilẹ baba ẹnikan - irọ ni. Yoruba lo ni Ekoo - irọ naa tun ni. Ekoo jẹ ilẹ ati ibi ti awọn ẹya Yuroopu n lo fun okoowo ẹru - otitọ ree!!
"Ẹ ko mọ Ekoo!! #getthesax
"Iwọ, ọdẹ wo bii, ỌRỌ AWỌN ARA PỌTUGA. SLAVE COAST ni wọn pe e. Ẹ kọ nipa itan yin, ẹ ko nii gba.
"Awọn eeyan ko lọ si iluu Ekoo lati ṣe owo ẹru ni. Awọn agbaagba ilu Ekoo ni wọn n ṣe okoowo ẹru. Ẹ daabo bo awọn ọga yin!! #getthesax. "
No comments:
Post a Comment