Nitori ọrọ ilẹ, wọn fẹsun jibiti kan ṣọọṣi Katoliiki l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, March 3, 2023

Nitori ọrọ ilẹ, wọn fẹsun jibiti kan ṣọọṣi Katoliiki l'Ogun


Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, afaimọ ni ki wọn ma pada le ṣọọṣi Katoliiki kan ti wọn pe ni
St Alphonsus Catholic to wa niluu Akute, ipinlẹ Ogun danu, iyẹn bi otitọ ba pada foju han wi pe wọn ko lẹtọọ lati kọ ṣọọṣi naa sibi to wa.
 
Ọkunrin kan ti wọn pe ni Ọgbẹni Babatunde Ọlalekan Lawal to n gbe lojule kẹẹdogun, adugbo Church to wa ni Ọpẹbi, Ikẹja, ipinlẹ Ekoo ni wọn lo gbe ṣọọṣi naa lọ sile ẹjọ.
 
Yatọ si ṣọọṣi yii, awọn yooku ti Lawal tun gbe lọ sile ẹjọ giga ipinlẹ Ogun to wa niluu Ọta ni Hakeem Fabolude, Samson Fabolude, Rasheed Fabolude ati Yaya Ogundimu, to si fẹsun jibiti kan wọn.
 
Lara ẹsun to fi kan wọn ni pe wọn gba ile ati ilẹ oun lọna aitọ, wọn tun wo ile oun lati fi kọ ṣọọṣi naa si, eyi to loo lodi si ofin, lẹyin toun ti gba gbogbo iwe to yẹ lori ọrọ ile ati ilẹ lọdọ ijọba.
 
Lawal ninu iwe ẹsun naa ti nọmba rẹ jẹ HCT/861/19, pẹlu deeti ọjọ keje, oṣu kẹsan, ọdun 2020 lo ti ṣalaye pe awọn eeyan naa wo ile oni yara mẹrin aladagbe, iyẹn four-flat building to wa lagbegbe Tunde Senbanjo Crescent, Akute, ti wọn si tun fipa gba ilẹ pulọọti mẹta ataabọ. toun kọ ile naa si lori lọwọ oun.

Ẹsun naa ti agbẹjọro A T Badmus pe, lo ti sọ pe ṣọọṣi naa lẹdi apo pọ mọ Yaya Ogundimu, ẹni to pe ara rẹ ni oṣiṣẹ ilẹ ni wọn le ẹgbọn oun obinrin to n gbe inu ile naa, ati awọn ayalegbe toun gba sile danu lọdun 2013, ko to di pe wọn da ile oun wo, ti ijọ Katoliiki naa si gba a lati fi kọ ile ijọsin wọn.

Lawal ni ọdun 1990 loun ra ilẹ pulọọti mẹta ataabọ lọwọ mọlẹbi Fabolude, nipasẹ ẹgbọn oun obinrin, Arabinrin Adebayọ Oluwatoyin, toun si ṣe gbogbo iwe to tọ lọdọ ijọba lẹyin toun de lati ilu Oyinbo lọdun 1992.
 
O ni lẹyin naa loun kọ ile sori ẹ fun gbigbe ati ayagbe toun gba awọn tẹnanti si. Ọkunrin naa loun gba iwe 'emi ni mo ni ilẹ' {Survey Plan and Certificate of Occupancy}, eyi to jẹ ojulowo lọdọ ijọba.

Siwaju sii lo sọ pe oun ti n gbadun ile ati ilẹ naa, to si jẹ iyalẹnu wi pe lọdun 2013 ni Yaya Ogundimu de, to si le ẹgbọn obinrin ati awọn ayalegbe danu, pẹlu ẹtanjẹ wi pe oun ti gba iwe idajọ to sọ pe oun laṣẹ lori dukia naa.
 
O ni Yaya Ogundimu ko ko iwe ile ẹjọ silẹ foun tabi ẹgbọn oun to n gbe inu ile naa, Arabinrin Ọlayinka Rufai.
 
Bakan naa lo tun sọ pe yatọ si pe Yaya ko fi iwe idajọ kankan ti nọmba rẹ jẹ HCT/401/2005 han oun, sibẹ ko tun sọ otitọ fun ile ẹjọ wi pe idajọ ti nọmba rẹ jẹ HCL/24/81 ti de ile ẹjọ kotẹmilọrun lati tako o.
 
Nigba to n tẹsiwaju, Lawal sọ pe lakoko kan toun wa si Naijiria, o ni ijọ St Alphonsus Catholic Church ti wa ba oun lati ta ilẹ naa foun, lati fi kọ ṣọọṣi si, ṣugbọn toun sọ fun wọn pe oun ṣi fẹẹ lo o.

O ni lẹyin rẹ ni wọn lọ lẹdi apo papọ mọ Yaya lati tọwọ bọwe adehun, ki wọn si gba ilẹ naa lọwọ oun lọna aitọ, eyi to sọ pe ko bojumu to.
 
Bakan naa lo tun jẹ ko di mimọ pe lọdun 2012 bu idile Fabolude wa ba oun wi pe oun ni lati tun owo san, lati le jẹ ki wahala to wa lori dukia oun d'ohun igbagbe, to si loun san miliọnu kan naira fun wọn, ṣugbọn to tun sọ pe iyalẹnu lo jẹ wi pe wọn tun gbọna ẹyin lọ ta ilẹ ati dukia oun lẹyin.
 
Lawal wa rọ ile ẹjọ lati gba dukia oun pada f'oun, ki wọn si san miliọnu lọna ọgbọn naira, gẹgẹ bi owo itanran dukia oun ti wọn da wo lulẹ lati fi kọ ile ijọsin si.
 
Yatọ si pe Lawal n bẹ ile ẹjọ lati paṣẹ wi pe oun loun ni dukia naa, o tun ni ki ile ẹjọ da gbogbo awọn toun fẹsun kan lọwọ kọ lati de ori ilẹ naa, ati pe ki ijọ Katoliiki naa gbe ijọ wọn kuro lai fi akoko ṣofo.

Ni bayii, a gbọ pe Onidajọ tuntun ti wọn gbe si iṣakoso ẹjọ naa, Onidajọ O. O. Ọṣunfisan ti sun igbẹjọ siwaju si ọjọ kẹta, oṣu karun-un, ọdun 2023.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI