Ki Tinubu ma tii yọ layọju, Oun pẹlu INEC n tan ara wọn jẹ lasan ni - Adebanjọ, olori Afẹnifẹre sọrọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, March 3, 2023

Ki Tinubu ma tii yọ layọju, Oun pẹlu INEC n tan ara wọn jẹ lasan ni - Adebanjọ, olori Afẹnifẹre sọrọ


Olori ẹgbẹ Afẹnifẹre, Alagba Ayọ Adebanjọ ti sọ pe ki oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu ma tii yọ layọju, nitori pe oun kọ lo jawe olubori ninu eto idibo apapọ ọdun 2023 to waye lopin ọsẹ to kọja.

Alagba Adebanjọ sọ pe ko tii si Aarẹ tuntun ti wọn dibo yan ni Naijiria lasiko yii, ati pe ipinnu ajọ eleto idibo, iyẹn Independent National Electoral Commission, INEC ko le f'ẹsẹ mulẹ lailai.

Fawọn ti ko ba mọ, Alagba Adebanjọ wa lara awọn agba ilẹ Yoruba ti wọn kede nita gbangba wi pe oludije sipo Aarẹ lẹgbẹ oṣelu Labour, iyẹn Peter Obi loun yoo ṣatilẹyin fun, nitori bo ṣe sọ pe awọn ara agbegbe Guusu-Ila-Oorun naa ni lati jẹ anfaani ipo Aarẹ.

Nigba to n farahan lori amohunmaworan Arise lonii ọjọ Ẹti, Furaidee, Adebanjọ sọ pe magomago wa ninu eto idibo naa, eyi to sọ pe ko boju mu to fun idagbasoke Naijiria.

“Mo gbọ nigba Dino Melaye sọ fun alaga INEC wi pe ko ṣi da kika esi ibo naa duro fungba diẹ lati fi ṣe atunṣe lori awọn agbegbe ti kudiẹ-kudiẹ wa, ṣugbọn ti alaga naa sọ pe bi Melaye ba gba oun laaye lati ka esi ibo naa tan, oun yoo tun ṣe agbeyẹwo rẹ.

“Fun alaga INEC, ọpọ awa ti a mọ ọn la mọ pe kii ṣe iru eeyan to yẹ ko jẹ ni. Ajanikulẹ nla lo jẹ. Kii ṣe igba akọkọ ree ti yoo maa ja awọn ara Ekoo kulẹ.

"Lọdun 2019, o tan wa jẹ, bẹẹ lo tun ti tun un ṣe bayii, pẹlu erongba wi pe omugọ l'awọn ọmọ Naijiria. 

“Mo si ti sọ ọ ṣaaju idibo yii wi pe ko sẹni to le Babangida wa. Ole ọsan gangan ni wọn ja wa. Gbogbo orileede yii lo fọwọsowọpọ pẹlu ẹ lati ṣatunṣe lori ofin ati ilana eto idibo, iyẹn 'electoral law', lati rii wi pe wọn gbe ibo sita nipa ilana idibo, to si jẹ pe lakoko idibo, niṣe lo pada wa ba wa ja. Itiju nla lo jẹ. O kan ṣe mi laanu fawọn ọmọ Naijiria lasan ni.

“Aanu awọn ọdọ lo ṣe mi. Ṣugbọn mo kilọ fun un yin tẹlẹ, ajalu nla ni ijọba yii jẹ...ajalu ti Ọlọrun yoo jẹ ka bori rẹ ni.

"Ko tii si oludije ti wọn dibo yan rara. O da mi loju pe wọn yoo yọ ọ danu laipẹ. Gbogbo wa la maa foju wa rii laipẹ. Ki lo de ti a ko le tẹle ilana ofin to wa nilẹ fun idibo.?

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI