O ga o! Ọmọ ogun ọdun pokunso l'EKoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, March 26, 2023

O ga o! Ọmọ ogun ọdun pokunso l'EKoo


Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii tan ni ko tii sẹni to le sọ pato idi ti ọmọ ogun ọdun kan, Sọdiq Ọlayẹmi ṣe deedee gbẹmi ara rẹ nipa pipokunso, sibẹ ileeṣẹ ọlọpaa Ekoo ti jẹ ko di mimọ pe iwadii awọn ti bẹrẹ.
 
Inu ile akọku kan la gbọ pe Sọdiq pokunso si lagbegbe Ẹpẹ n'ipinlẹ Ekoo lọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii.

Awọn to fi iroyin naa to wa leti sọ pe awọn ara adugbo ni wọn deedee ri oku Sọdiq ninu ile akọku naa, ko to di pe wọn sare lọ sọ fun mama rẹ.

Ki oloju to o ṣẹ ẹ, wọn ni ero ti peju sibẹ, ti onikaluku si n sọ ohun ti oju wọn to, ati eyi ti ko to.
 
Mama Sọdiq lo pada pe baba rẹ, lati fi to o leti wi pe ọmọ rẹ ti gbẹmi ara rẹ. Loju ẹsẹ ni baba naa ti gba teṣanọlọpaa lọ lati fi to wọn leti.

Awọn ọlọpaa ni wọn pada lọ gbe oku naa kuro lọ mọṣuari lati ṣayẹwo, ti ayẹwo si fidi rẹ mulẹ pe funra Sọdiq lo gbẹmi ara rẹ, kii ṣe pe wọn f'ipa mu.
 
Bakan naa la gbọ pe iwadii ọlọpaa ti bẹrẹ lati mọ ohun to ṣẹlẹ ni pato.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI