Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii lọrọ iku gbajugbaja oṣerebinrin nni to ṣẹṣẹ n dide bọ, Akingbemisọla Dorcas Anjọla ṣi n jẹ fun ọpọ awọn to gbọ.
Ọjọ Satide, Abamẹta to kọja yii la gbọ pe Anjọla jade laye, lẹni ọdun mẹtalelọgbọn.
Aisan jẹjẹrẹ oju ara ti awọn oloyinbo n pe ni Ovarian cancer ni wọn lo kọlu ọmọbinrin naa, to si pada gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.
Ọdun 2021 ni iroyin fi to wa leti pe Anjọla lọ ṣayẹwo niluu Dubai, orileede United Arab Emirates, nibi to ti gba itọju fun ọpọlọpọ oṣu.
Lẹyin itọju, ti awọn dọkita ko si ri nnkankan mọ, ni wọn sọ pe ko maa lọ sile, eyi lo jẹ ki Anjọla pada si Naijiria lati bẹrẹ iṣẹ tiata rẹ pada.
Wọn ni lojiji ni aisan tun bẹrẹ sii lara, to si loun ko mọ bi ara ṣe n ṣe oun. Idi ree to tun fi gba ọsibitu lọ fun itọju, ti aisan naa si n peleke sii.
Ori aisan naa lo pada dakẹ si, eyi to mu k'awọn akẹgbẹ rẹ kede iku rẹ sita.
No comments:
Post a Comment