O ti sẹẹti! Awọn obinrin ṣe iwọde ipolongo saa keji f'AbdulRazaq ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, March 12, 2023

O ti sẹẹti! Awọn obinrin ṣe iwọde ipolongo saa keji f'AbdulRazaq ni Kwara


Gbogbo awọn obinrin patapata kaakiri igboro, igberiko, abule ati ilu to wa n'ipinlẹ Kwara ni wọn ti jade sita lati sọ pe awọno ko fẹ ẹlomiran n'ipo gomina to kọja AbdulRahman AbdulRazaq. , ẹni to gbajọba lọdun 2019.
 
Agbarijọ awọn obinrin naa sọ pe iṣẹ gomina wọn, AbdulRazaq ṣi n tẹ awọn lọrun, eyi ti wọn fi n sọ pe saa keji rẹ ti daju.

Ẹsẹ ko gbero rara kaakiri ipinlẹ naa, nigba ti awọn obinrin yii tu jade lọpọ yanturu lati polongo wi pe Gomina wọn yii ni k'awọn araalu jade dibo fun lakoko idibo to n bọ lọjọ Abamẹta, Satide, to n bọ lọna yii.
 
Wọn ni yatọ si pe Gomina AbdulRazaq n ṣe bẹbẹ nipinlẹ naa nipa awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke, ko tun yọwọ awọn obinrin kuro ninu iṣakoso rẹ, pẹlu bo ṣe fi awọn obinrin s'ipo to jọju ninu eto oṣelu.

Lara alakalẹ eto ayajọ ọjọ awọn obinrin to waye laipẹ yii l'awọn obinrin ipinlẹ fi imọriri wọn han, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe awọn ko nii pada sẹyin lati dibo fun gomina mẹkunnu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI