Ọkọ at'iyawo ku sori ara wọn n'Ilaro - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, March 3, 2023

Ọkọ at'iyawo ku sori ara wọn n'Ilaro


Kayeefi nla lọrọ iku ọkọ ati iyawo kan ṣi n jẹ titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii tan, lori bi wọn ṣe ku sori ara wọn, ti ko si tii sẹni to le ṣalaye ohun to ṣokunfa fa iku wọn.
 
Kẹhinde Ẹgbẹyi, ẹni ọdun mẹtadinlogoji to yan iṣẹ agbẹ laayo ati iyawo ẹ, Bukọla la gbọ pe wọn ba oku wọn ninu ile ti wọn n gbe lagbegbe Oke Erinja to wa loju ọna Ilaro si Owode, ijọba ibilẹ Guusu Yewa, ipinlẹ Ogun.
 
Ile ọkan lara awọn mọlẹbi wọn ti wọn pe ni Joel ni wọn n gbe, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
A gbọ pe wọn ṣi wo ẹrọ amohunmaworan lalẹ ọjọ to ṣaaju ọjọ iku wọn, ko to di pe wọn gba inu yara wọn lọ sun si.
 
Wọn ni awọn eeyan ti jade laarọ ọjọ naa lati lọ sibiṣẹ oojọ wọn, ti wọn si lawọn mejeeji ko jade sita lati lọ sinu oko, gẹgẹ bi wọn ṣe maa n lọ, eyi si ni wọn lo jẹ iyalẹnu f'awọn ti wọn jọ n gbe.
 
A gbọ pe Joel pe Kẹhinde lati jade sita, nitori toun fẹẹ jade lọ, ṣugbọn ti ko gbọ ohun ẹnikẹni ninu tọkọ tiyawo naa.
 
Wọn ni bo ṣe jẹ iyalẹnu fun Joel, lo jẹ ko lọ pe awọn ara adugbo, ti wọn si ni ṣe ni wọn ja ilẹkun yara wọn wọle.
 
Kayeefi nla lo jẹ nigba ti wọn ba oku awọn mejeeji lori bẹẹdi, ti ko si sẹni to le ṣalaye iru iku to pa wọn.
 
Ọkan lara awọn to b'oniroyin sọrọ sọ pe awọn mejeeji yii ko fi apẹẹrẹ kankan han tẹlẹ wi pe ara wọn ko ya, o ni digbi lara wọn ya, ko si si nnkan to ṣe wọn.
 
Ẹni naa sọ pe kete t'awọn ti ba oku wọn ninu yara ni wọn ti fi to awọn ọlọpaa leti
 
Wọn ni niṣe ni ẹjẹ n da ni inu Kẹhinde, ti foomu funfun si n jade lẹnu iyawo rẹ Bukọla nigba ti wọn ba oku wọn lori bẹẹdi laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.
 
Lara awọn akiyẹsi ti wọn lawọn kan ṣe ni pe o ṣee ṣe ki iku wọn wa lati ara eefi jẹnẹretọ ti wọn tan.
 
A gbọ pe lati mọ iru iku to pa ọkọ atiyawo yii, awọn mọlẹbi gba ile babalawo lọ lati beere lọwọ ifa, ti wọn si tun gba teṣan ọlọpaa lọ lati fi to wọn leti.
 
Wọn ni b'awọn ọlọpaa ṣe sọ pe ki wọn lọ ṣayẹwo iru iku to pa awọn mejeeji, lawọn mọlẹbi ti sọ pe awọn ti gba kadara wi pe amuwa Ọlọrun ni, ti wọn si ti sinku awọn mejeeji loju ẹsẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI