Ọlọrun ko lọwọ si bi Tinubu ṣe fẹẹ di aarẹ Naijiria, ijakulẹ nla ni yoo jé f'awọn araalu - Wolii Ayọdele - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, March 3, 2023

Ọlọrun ko lọwọ si bi Tinubu ṣe fẹẹ di aarẹ Naijiria, ijakulẹ nla ni yoo jé f'awọn araalu - Wolii Ayọdele


Alaṣẹ, apaṣẹ ati oludasilẹ ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, Wolii Elijah Ayọdele ti sọ pe Ọlọrun ko si lẹyin bi Bọla Ahmẹd Tinubu ṣe jawe olubori ninu eto idibo apapọ to waye l'opin ọsẹ to kọja yii, to si ni ifasẹyin ni yoo jẹ f'awọn ọmọ Naijiria.

O ni ijọba to n labẹ iṣakoso yoo kun fun ibanujẹ, ilakaka, ikuna ati ijakulẹ ninu eto ọrọ aje orileede Naijiria
 
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin Wolii Ayọdele, iyẹn Ọgbẹni Oluwatosin Ọṣhọ fi ranṣẹ s'AWIKONKO l'ọsan oni, ọjọ Ẹti, Furaide, o ni ko si nnkan ti iṣakoso to n bọ yoo fi dara ju eyi to wa nibẹ lasiko yii, nitori pe niṣe ni wọn ji erongba awọn araalu gbe.
 
O ni ko si ninu ipinnu Ọlọrun wi pe awọn ẹlẹsin Kristẹẹni ko nii si ninu eto akoso orileede Naijiria, ati pe ẹgbẹ oṣelu APC fẹẹ da rukerudo ati rudurudu silẹ l'ẹka eto ẹsin ni.
 
Mo n ri ijọba tuntun to kun fun ibanujẹ, ilakaka, ikuna, ijakulẹ ninu eto ọrọ aje, niṣe ni gbogbo nnkan yoo le koko nitori pe Ọlọrun ko fọwọ si ijọba APC miran fawọn ọmọ Naijiria.
 
“Labẹ iṣakoso yii, wọn ko nii bu iyi kun Naijiria lagbaye, ijọba yii ko nii ṣe daadaa bii ti ijọba to fẹẹ kuro nibẹ.
 
“Ijọba yii kii ṣe eyi ti Ọlọrun fi ọwọ si fun wa. Ọlọrun ko tii fi ọwọ sii lati jẹ orileede ẹlẹsin musulumi, ko tii sọ pe awọn Kristẹẹni ko nii si ninu ilana ato eto iṣejọba yii, ṣugbọn awọn wọnyi fi oju yẹpẹrẹ Ọlọrun, wọn fẹẹ da rukerudo silẹ lẹka eto ẹsin, ṣugbọn Ọlọrun ti kọ wọn silẹ.’’

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI