'Ọmọ Yahoo' meje dero atimọle l'Abuja - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, March 29, 2023

'Ọmọ Yahoo' meje dero atimọle l'Abuja


Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ati jibiti lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission, ẹka tiluu Abuja ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ awọn gendekunrin meje kan ti wọn ko niṣẹ meji ju iṣẹ jibiti ori ayelujara lọ.
 
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ana, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹta, ọdun ti a wa yii ni ajọ EFCC sọ pe ọwọ awọn tẹ awọn meje naa lori ẹsun jibiti ori ayelujara ti a mọ si 'Yahoo-Yahoo' lọ.
 
Peter Omega Awupri, Philip Okonkwo, Emeka Okonkwo, Williams Chukwu, Stephen Anthony, Edobor Osas ati Adetọla Sunday lọwọ palaba wọn segi lagbegbe Gwarimpa, niluu Abuja.
 
Wilson Uwujaren to jẹ agbẹnusọ ajọ EFCC nigba to n ṣalaye, sọ pe olobo kan lo ta awọn, ti wọn fi bẹrẹ iṣẹ iwadii, ko to di pe ọwọ tẹ wọn.
 
Foonu mẹjọ, ẹrọ kọmupta alegbeeka mẹrin, iwe irinna mẹta, aago olowo nla, mọto Lexus  ati Toyota ni wọn gba lọwọ wọn, to si ni lẹyin iwadii lẹkunrẹrẹ lawọno yoo foju wọn ba ile ẹjọ.
 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI